Iyabọ Ojo Ṣalaye Idi To Fi Gba Ki Baba Priscilla Sin Lọ Ile-ọkọ

Iyabọ Ojo Ṣalaye Idi To Fi Gba Ki Baba Priscilla Sin Lọ Ile-ọkọ

Gbajumọ oṣere to tun jẹ alafẹ, Iyabọ Ojo lo ti sọ f’aye gbọ idi to ṣe gba ki ọkọ rẹ atijọ to tun jẹ baba awọn ọmọ rẹ o yọju gẹgẹ bii baba iyawo ni’bi ayẹyẹ igbeyawo alarinrin to ṣe fun ọmọ rẹ obinrin ìyẹn Priscilla l’ọjọsi, ni oṣu kẹrin ọdun 2025.

Iyabọ Ojo s’ọrọ yii l’ori eto “The Morayo Show.” Alaye rẹ ni pe igbesẹ gbọdọ wa’ye bi eniyan ba fẹ pa egun rẹ.

O ni awọn obi oun ti kọ ara wọn, oun naa pẹlu ti ni iriri kikọ ọkọ ṣugbọn ti oun ti ṣe ipinnu pe eyikeyi ilakọja oun ko ni la ipa buruku l’ori awọn ọmọ oun.

Eyi gan-an lo fa ti oun fi pinnu l’ọkan oun pe oun yoo fi igbesẹ gbigba baba Priscilla l’aaye lati ṣe baba iyawo l’ọjọ nnkan ẹyẹ ọmọ rẹ ra idunnu ati aṣeyọri fun igbeyawo ọmọ oun.

O fikun pe, nigba ti ọjọ ẹyẹ Priscilla ti ba baba rẹ l’aye, ko si idi kankan lati ma jẹ ko wa ni’bẹ. Ati pe ohun yowu to wu ko ti ṣẹlẹ l’aarin oun ati ọkọ rẹ atijọ, ko yẹ ko kan awọn ọmọ rara nitori ko ṣẹ wọn.

“Mo fi igbesẹ naa ra aṣeyọri fun ọmọ mi ni, ko le ri idunnu ni’le ọkọ; baba rẹ o ku; o wa l’aaye, ki lo de ti ko ni wa ni’bẹ?. Igba ki ko ṣẹ ẹ; emi pẹlu rẹ la o jọ si papọ mọ, ko si gba ibi kankan kan,” Iyabọ Ojo wi.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search