Gbajugbaja olukopa lori eto ori amohunmaworan BBNaija, Mercy Eke ti sọ pe bi o tilẹ jẹ pe eto agbelewo Big Brother Naija ṣe ayipada rere si aye oun, niṣe l’oun kabamọ pe oun lọ nitori awọn ipenija to wa pẹlu jijẹ gbajumọ.
Nigba to n sọrọ lori eto kan ti wọn pe si, o ni pipada si igbesiaye t’oun n gbe tẹlẹ nira lẹyin eto naa. O ni koda, niṣe l’oun pada kuro l’orile-ẹde Naijiria lọ s’oke okun lati wa iṣẹ k’oun le tun aye oun bẹrẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni lootọ awọn anfaani to pọ lo wa pẹlu b’oun ṣe gbegba oroke ni’bi eto naa ṣugbọn, bi oju gbogbo aye ṣe wa lara oun ti jẹ ko su oun.
O ni ọpọ awọn eeyan lo jẹ pe awọn gbajugbaja ni wọn ma n fi ikanra ohun to n ṣẹlẹ si wọn mu, nitori o maa n wun wọn lati gbe igbesiaye ti awọn n gbe.
Mercy Eke ti inagijẹ rẹ n jẹ Lambo lo ja gbangba gẹgẹ bi obinrin akọkọ lati gbe’gba oroke ni’bi eto agbelewo Big Brother Naija ni ọdun 2019.