Ẹ Ni Suuru Fun Tinubu, Kii Ṣe Ọlọrun - Jide Kosoko
Agbaojẹ oṣerekunrin, Jide Kosoko ti ṣatilẹyin fun iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu, to si n sọ pe kii ṣe ẹni to pe tan nitori naa ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria fun ni asiko diẹ ko to di pe wọn maa ṣe idajọ awọn akanṣe iṣẹ to n ṣe.
Nigba to n sọrọ lori ifọrọwanilẹnuwo kan, Kosoko jiyan pe o ti ya ju lati maa ṣe idajọ iṣejọba ọhun, bẹẹ lo n fi iṣejọba we ile kikọ.
O ni bi eeyan ba n kọ ile, o di’gba ti ile naa ba pari ki eeyan to le mọ boya o dun wo. Oṣerekunrin naa ni, lootọ Aarẹ Tinubu o le da tan nitori kii ṣe ọlọrun.
Kosoko ni awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu alatako n mọọmọ yi ero awọn araalu paapaa julọ awọn ọdọ pada laida si iṣejọba to wa l’ode yii. O ni wọn mọ pe awọn ọdọ ṣe yi lọkan pada kia lati le ri wọn lo.
O tẹsiwaju pe koda, awọn ajijangbara gan o da iṣẹ ara wọn jẹ niṣe ni wọn n gba owo lọwọ ijọba.
O ni ṣugbọn ti awọn ba jade sọrọ, awọn eeyan a fẹsun kan awọn pe ijọba ti gb’owo f’awọn lai ṣe pe awọn o le da inu ro tabi nkan rọgbọ f’awọn ati awọn mọlẹbi awọn.
Bi o tilẹ jẹ pe agba oṣere naa kin iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu lẹyin, o ni oun gba pe lootọ, nkan le gan fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ṣugbọn pinpin owo kọ ni ọna abayọ nitori bi awọn eeyan ile ṣe pọ to, nitori naa, awọn eeyan gbọdọ ni suuru ki awọn atunṣe naa gbina ya.