Boya Lẹ Mọ Pe Eegun Kan N Bẹ Ni’badan Ti Kii F’oju R’obinrin?

Boya Lẹ Mọ Pe Eegun Kan N Bẹ Ni'badan Ti Kii F'oju R'obinrin?

L’ara awọn aṣa ati iṣẹ to gbajumọ daadaa nilẹ Yoruba ni egungun abi eegun, ti wọn a tun ma pe ni ara-ọrun. Igbagbọ Yoruba ni pe awọn alalẹ ni ko gbagbe awọn ara aye, ti wọn si n fi eegun ṣe abẹwo si wọn, ati iranwọ ni’gba ti wọn nilo rẹ. Oriṣiriṣi ni eegun, wọn yatọ ni irisi, iṣe, itan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ ṣa, ninu awọn eegun to gbajumọ ni ilẹ Yoruba paapaa julọ ni ilẹ Ibadan ni eegun ti wọn n pe ni “Oloolu” eegun yii wọn gba pe o l’agbara julọ ninu gbogbo eegun ni’badan. Eegun kan to ti gbiyanju ta Oloolu l’aya ni “Ipọnri Iku”.  Bo ṣe danwo lo dan tan. Itan jẹ ko ye pe nigba aye Olubadan Dada ni awọn eegun meji koju ara wọn, ti Oloolu si ju owo ẹyọ silẹ fun Ipọnri Iku lati mu nilẹ ṣugbọn ti iyẹn da ni eegun ẹyin, to si gba ibẹ ku.

Ni’bi ti eegun Oloolu gbayi gbajumọ de, ọdọdun ni awọn Ibadan ma n ṣe ajọdun eegun naa. Koda asiko t’ọdun 2026 la wa yii. Ajọdun eegun l’apapọ lo ti bẹrẹ lati ọjọ Aiku (Sunday) ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ọdun 2026, ti yoo si pari ni ọgbọn’jọ oṣu keje ọdun 2026 bakanna.Ijade eegun Oloolu gan-an ni wọn yoo fi kadi gbogbo ayẹyẹ naa ni’lẹ.

Gẹgẹ bii atẹjade amọran Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Adewọlu Ladọja Aruṣa Kinni l’ori ọrọ ọdun Oloolu pe ki wọn fi ẹsọ ṣe ki wọn si gba alaafia l’aaye.

Ni’bamu pẹlu alakalẹ eto, ọjọ Aje (Monday) to n bọ ni eegun Oloolu yoo ja’de, ti yoo si kọkọ lọ sure fun Olubadan, ati gbogbo ilu, ti yoo si tun de ọdọ Ọtun Olubadan. Ọjọ Iṣẹgun (Tuesday) ni yoo de ọdọ Gomina Ṣeyi Makinde ni ọfisi rẹ ni Agodi, ko to wa lọ Ali-Iwo, Yemẹtu, Ọja Oje, Isalẹ-Afa, Oke-Arẹmo, Popo-Yemọja, Ọja Bode, Molete, Isalẹ-Ijẹbu, Elekuro, Kobomọjẹ ati Ọranyan. Ọjọ kẹta to jẹ Ọjọru (Wednesday) ni yoo de Ọjagbo, Alafara, Olubadan, Ita-Baalẹ, Ogboriẹfọn, Labọ. Ọjọbọ Thursday to gbẹyin ni Oloolu yoo de Ile-Aperin, Agugu, Iyana Idi-Iroko, Awotunde, Jegede, Itamẹrin, Ganganṣi, Babanla.

Bi eegun ti wa l’okiki to, eewọ pe kii f’oju kan obinrin l’asiko to ba ja’de tun jẹ ki ọrọ eegun naa di ẹrujẹjẹ ni’bi kibi. Koko ohun to si bi eyi ni pe l’asiko ogun kan lati’jọ niluu Ogbagi, ni’pinlẹ Ondo ni akinkanju jagun-jagun kan ti mu eegun naa l’oju ogun wa si’le ṣugbọn to pada pẹ paṣẹ ki wọn bẹ ori iyawo ẹni to ru ẹku naa ni’gba to taku l’oju ọna pe oun o b’awọn lọ mọ. Ori iyawo titi d’oni wa l’ara ẹku Oloolu to di’fa fun idi ti Oloolu kii fi f’oju kan obinrin nitori o le bi ewu to pọ.

Idile jagunjagun Ayọrinde Aje to mu Oloolu wa si Ibadan to si fun l’orukọ naa lo ṣi n ṣe itọju rẹ titi di oni, bẹẹ ba ti bere ile Aje ni Ode Ajẹ ni’badan, ọdọ awọn arọmọdọmọ Aje le wa n.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search