Wahala De L’Ọṣun, Wọn Fi Iku Wa Iyawo AMBO To Fẹ Ṣe Gomina Kiri

Wahala De L'Ọṣun, Wọn Fi Iku Wa Iyawo AMBO To Fẹ Ṣe Gomina Kiri

Ni bi eto idibo gomina nipinlẹ Ọsun ṣe ku si dẹdẹ bayii, n ṣe ni oṣelu kan n gbona giri yatọ nipinlẹ naa.

Awọn agbebọn ni aabọ iroyin fi ye’ni pe wọn ṣe ikọlu si ọwọ-ọkọ iyẹn ‘convoy’ Abilekọ Sekinat Oyebamiji ẹni tii ṣe aya fun oludije si’po gomina nipinlẹ Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn Aṣiwaju Munirudeen Oyebamiji ni agbegbe kan ni ijọba ibilẹ Guusu Ede.

Ikọlu naa lo wa’ye ni nnkan irọlẹ ọjọ Aiku (Sunday) anaa ni agbegbe Alajuẹ, to n bẹ ni Wọọdu keji, ni gẹrẹ ti Abilekọ Oyebamiji ṣe’pade ati abẹwo s’awọn eeyan at’awọn alatẹle wọn ṣaaju idibo ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹjọ to ti de tan.

L’ara awọn ti wọn jọ k’ọwọ rin l’asiko naa ni Ọmọ-Ọba Bukọla Adereti to jẹ aya igbakeji oludije si’po gomina ninu ẹgbẹ APC, Alhaji Kayọde Adereti.

Awọn agbebọn naa ni aabọ iroyin fi ye’ni pe wọn to bi mẹẹdogun (15) ni’ye, ti wọn si ṣe ikọlu naa ni nnkan aago meje aṣalẹ (7pm) ni gẹrẹ ti Abilekọ Oyebamiji n fi ibi eto naa si’lẹ.

Botilẹjẹ pe ori ko awọn mejeeji yii yọ ninu ikọlu naa, a mọ ṣa, elomiran ti wọn juwe gẹgẹ alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW ni ẹka ti ilu Sẹkọna, ni’pinlẹ Ọṣun lo f’ara gb’ọgbẹ gidi gan-an ninu iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search