Haaaa, Eyi O Da O, Wọn Lu Peller Ni Jibiti L’ẹyin Igbeyawo Ẹ

A ṣe wọn lu gbajugbaja ori ayelujara, Peller ni jibiti l’ọjọ igbeyawo rẹ. Lẹyin ti Peller ṣe igbeyawo alarinrin pẹlu aya rẹ Jarvis ni opin ọsẹ to kọja ni aṣiri jibiti nla ti wọn lu Peller ṣẹ tu si’ta.

Ṣẹ kuku mọ pe wọn tun ti da’jọ aṣekagba ayẹyẹ igbeyawo onipelejipele naa si opin ọsẹ ta wa yii, l’ọjọ Abamẹta (Satide).

Amọ ṣ, l’aarin asiko ayẹyẹ igbeyawo mejeeji yii oniruru aṣiri n tu si’ta. Ọtọ ni t’awọn ti Peller ka orukọ wọn si’ta pe oun o fẹ ri ni’bi ayẹyẹ to gbẹyin yii gẹgẹ bi a ti ṣe fi abọ rẹ jẹ yin ṣaaju.

Ọtọ tun ni oniruuru awọn eniyan ti ẹrọ ibanisọrọ wọn poora ni’bi ayẹyẹ naa to mu ki Peller ṣe ikilọ pe awọn ko ni gba gbẹrẹ rara ni pati (party) eyi to n bọ.

L’ọwọ yii, ọrọ jibiti ti wọn lu Peller ni aṣiri tuntun to tun ṣẹṣẹ jade wa. Peller lo si sọ ọrọ naa di mimọ l’asiko to wa ni oju-opo TikTok pe awọn eeyan fa oun l’ori l’ọjọ igbeyawo oun, ti wọn si tun f’ọda kun.

Peller ni, oun k’owo de banki tan ni wọn ja oun si pe kii ṣe gbogbo owo naa lo jẹ ojulowo. O fi kun pe, oun mọ awọn to naa owo gidi f’oun, oun mọ wọn t’oun ba ri wọn.

B’awọn kan ti n pe iwa buruku gbaa ni jibiti ti wọn lu Peller yii o, awọn miiran ni ṣebi alare kuku oun naa tẹlẹ pe, ere naa lo de’bẹ ti wọn ba n na ara wọn ni owo ofege.

L’aarin iyẹn naa ni ọrọ awuyewuye miiran pe Ṣeun Kuti bi’nu kuro nibi ode igbeyawo Peller nitori awọn atọkun eto da’para pe Wizkid tobi ju Fẹla lọ ni’di iṣẹ orin. Ṣeun lo tan imọlẹ s’ọrọ naa nigba ti gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Sule Alao Malaika koju rẹ l’ori ọrọ naa. Amọ ṣa, Ṣeun ni ọrọ ko ri bẹẹ rara nitori nnkan aagọ mẹjọ aabọ aṣalẹ l’oun kuro, t’oun si gba ibẹ lọ ‘Fẹla Shrine’ nitori awọn tun ni ṣiṣe kan ni’bẹ l’aṣalẹ ọjọ naa.

Ni’pa ti jibiti ti wọn lu Peller, alaye rẹ ni pe, ninu obitibiti owo ‘dollar’ ti wọn naa naa fun-un l’ọjọ inawo, ọpọ ninu rẹ lo jẹ ayederu ti kii ṣe ‘dollar’ gidi.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search