Agbabọọlu Nigeria, Troost-Ekong Ma Ti Di Musulumi!
Agbabọọlu William Troost-Ekong ti gbe igbesẹ gboogi ninu aye rẹ pẹlu bo ṣe ti gba ẹsin Islam l’orilẹ-ede Qatar.
Ẹni to jẹ balogun ikọ agbaojẹ orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ to ti n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Al-Ahli ni ligii ilẹ Qatar lo ṣe adura lati di Musulumi ni ilẹ Doha.
Ninu fọnran kan to ti tan ka bayii lo ṣafihan agba-owo-ẹyin naa to ṣ’adura t’awọn Musulumi n pe ni Shahada lati sami pe o ti gba Islam.
Troost-Ekong lo jẹ ọkan lara awọn agba-owo-ẹyin to gaayata l’orilẹ-ede Naijiria ko to di pe o fẹyinti nidi bọọlu f’orilẹ-ede.
Ọpọlọpọ ọdun lo ti lo gẹgẹ bi agbabọọlu n’ilẹEurope ko to di pe o bo si agbegbe awọn larubawa to jẹ ilẹ Arab.
Bi o tilẹ jẹ pe ko tii jade wa sọ idi to ṣe gba ẹsin Islam, ọpọ ariwisi lo ti tẹle gbigba ẹsin naa lat’ẹnu awọn ololufẹ bọọlu l’orilẹ-ede yii ati l’oke okun.