Lẹyin To Fi Agbo Orin Silẹ, Ẹ Wa Wo Ohun T'ọmọ Okoya N Ṣe Bayii
Raheem Okoya ti gbogbo eeyan mọ si Siraheem to jẹ ọmọ gbajugbaja olowo oniṣowo, Razaq Okoya, to kede pe oun ti kuro l’agbo orin laipẹ yii lo ti gbọn ẹsẹ rẹ pẹpẹ nidi orin lati wa nkan mii ṣe.
Onkọrin tẹlẹ naa lo fi awọn aworan kan lede lori ayelujara, eyi to ṣafihan rẹ lori ilẹ kan ti wọn n kọ lọwọ, to si n ni oun ti bẹrẹ iṣẹ lori ile ikọjasi akọkọ oun.
Awọn aworan ọhun ṣafihan Raheem nibi ilẹ ti wọn n kọ naa, t’awọn mii si n ṣafihan awọn ohun ti wọn fi n kọ ile ati awọn oṣiṣẹ lẹnu iṣẹ.
Gẹgẹ bo ṣe kọ s’abala ariwisi, o dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aabo gbogbo awọn ti wọn n ṣiṣẹ ni saiti naa, to si n ni bi o tilẹ jẹ pe ko ya b’oun ṣe fẹ, awọn ṣi n ṣiṣẹ lọ, fun idi eyi, ọpẹ lo gba.
Ti ẹ o ba gbagbe ninu oṣu kẹjọ ọdun yii ni Raheem kede pe oun ti fi agbo orin silẹ, to si ṣalaye pe orin kikọ ko rọgbọ lati mu mọ gbogbo awọn nkan mii t’oun n ṣe.
O dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, to si ni o ṣeeṣe k’oun fi awo orin kan sita lati kadi rẹ nilẹ pẹlu b’oun ṣe n tẹsiwaju lati mu nkan mii to niṣe pẹlu ọgbọn inu ati iṣowo gbọ.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn bu ẹnu atẹ lu orin rẹ ko to di pe o fi agbo orin silẹ, ti ọpọ si ni owo baba rẹ lo n gun.
Nibayi, awọn aworan yii ti fa ariwisi oriṣiriṣi lori ayelujara, bi awọn kan ṣe n lu l’ọgọ ẹnu, l’awọn kan ni nitori o jẹ ọmọ olowo lo ṣe rọrun fun, ti wọn si sọrọ lori pataki ki eeyan wa lati ile ọla.