Ẹ gbọ, ki lo n ṣẹlẹ laaarin Funkẹ Akindele ati Falz?

 

 

Loootọ ni ẹsẹ orin agba-ọjẹ onkọrin Juju nni, Oloye Ebenezer Obey lọ bayii: Falana, gbọ tiẹ, tara ẹni laa gbọ, sibẹ ọgọrọ awọn ololufẹ ilumọ-ọn-ka onkọrin hipọọpu nni, Fọlarin Falana, ti inagijẹ rẹ n jẹ Falz, ati awọn ololufẹ oṣere-binrin onitiata ti irawọ rẹ n tan bii oorun lagbo tiata lasiko yii, tawọn n kiyesi yii,  Funkẹ Akindele, tọpọ eeyan mọ si Jẹnifa, ni wọn ko le dakẹ, niṣe ni wọn n beere pe, ki lo n ṣẹlẹ laaarin Funkẹ ati Falz, ṣe ki i ṣe pe ọrọ

Funke Akindele (Jenifa) ati Folarin Falana (Falz)

ifẹ ikọkọ kan ti n waye, abi awọn mejeeji ti n ṣe kurukẹrẹ labẹnu, wọn lohun tawọn n kiyesi yii, afaimọ ni tuu ko ti fẹẹ maa ge fọọ fawọn gbajumọ mejeeji yii.

Ni tawọn mi-in, niṣe ni wọn n bẹbẹ lori ẹrọ ayelujara, wọn ni kawọn irawọ oṣere yii ma fi awọn sinu okunkun, ki wọn bọ si gbangba lati jẹ kawọn mọ bo ṣe n lọ, nitori ifẹ ti wọn ni sawọn mejeeji yii, awọn fẹẹ mọ nnkan to n ṣẹlẹ bo ba jootọ ni.

Ṣe Yoruba bọ, wọn ni ẹṣẹ ki i deede ṣẹ, ati pe, bi aja ko ba ri, aja ki i deede gbó, ohun to fa awuyewuye to n lọ lori ẹrọ ayelujara ati nigboro aye ko ṣẹyin iran awo-dami-ẹnu to waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, nibi afihan sinima tuntun ti Funkẹ Akindele ṣẹṣẹ ṣe, eyi to pe akọle rẹ ni Everybody Loves Jenifa, ọjọ yii ni wọn ko fiimu ọhun jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ.

Ẹsẹ ko gbero nibi ayẹyẹ ọhun, o fẹrẹ ma si ẹka ọrọ-aje ti ko pesẹ sibẹ tan, bawọn oloṣelu ṣe wa nikalẹ, lawọn olokoowo wa, ka ma ṣẹṣẹ sọ tawọn olorin lọlọkan-o-jọkan, agaga, awọn onitiata, fọfọ ni gbọngan iworan Imax Cinema, to wa ni Lekki, l’Erekuṣu Eko.

Yatọ si ti faaji famia to waye nibi eto ọhun, iran kan to gbafiyesi ni ti ijo alafẹ to waye loju agbo, ibi yii gan-an si ni Falz ati Jẹnifa ti ṣe ohun to kọ ọpọ eeyan lominu.

Ninu awọn fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lọwọlọwọ, o ṣafihan Funkẹ Akindele ati Falz, ọmọ gbajumọ ajafẹtọọ-ọmọniyan ati agbẹjọro to da-n-tọ nni, Alagba Fẹmi Falana, ti awọn mejeeji n jo ijo jẹlẹnkẹ, ijo ololufẹ, afi bii pe wọn n ṣere ifẹ tootọ ninu fiimu. Wọn ko si fi mọ sori ijo nikan o, wọn lo akoko to pọ lati jo, ọkunrin yii ni Funkẹ ba jo julọ, bẹẹ ni wọn di ara wọn lọwọ mu, bi Falz ṣe n woju Funkẹ bii igba ti ọkọọyawo n woju orente rẹ, bẹẹ ni Funkẹ naa gboju soke woju Falz, ifẹ si han kedere ninu ẹyinju awọn mejeeji, bi wọn ṣe n rẹrin-in musẹ, wọn tun lẹ mọ ara wọn pẹki, kinni naa si larinrin gidi, o fani lọkan mọra. Bẹẹ lawọn eeyan n ya fọto wọn loriṣiiriṣii.

Eyi ni diẹ ninu ọrọ tawọn ololufẹ wọn kọ lori fidio ijo ololufẹ wọn ọhun:

Bun Bright6 sọ pe: “Aa, idan to waye nibi yii pọ o.”

Sparkle Tea sọ pe: “Awọn mejeeji yii wa pa, wọn ṣe rẹgi.”

Taiwo Ibitomisin ni: “Ẹyin mejeeji, ẹ o ṣe kuku fẹ ara yin?”

Mo Cereals ni: “Mo nifẹẹ awọn mejeeji yii papọ, wọn nifẹẹ ara wọn”.

Hollar Pearl pariwo pe: “Aa, ifẹ ti gori afẹfẹ nibi yii o.”

Ibeere si ni Big Fish beere ni tiẹ, o ni: Iru iduro wa-mọ-tipẹ wo ni wọn ṣe fun ara wọn yii?” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Tẹẹ o ba gbagbe, lati bii oṣu diẹ sẹyin ni Fọlarin ti n dọgbọn sọrọ nipa ifẹ rẹ si Funkẹ Akindele. Nigba kan to ṣafihan awọn fọto ode ere to lọọ ṣe niluu London, lorileede United Kingdom lọhun-un, Falz ṣafihan bi awọn mejeeji ṣe jọọ wa papọ, ti wọn fijo da bira loju agbo, lẹyin naa lo sọrọ nipa boun ṣe fẹran Jẹnifa yii to, o ni oluranlọwọ gidi ni foun, ko si sigba toun nilo iranwọ rẹ ti kii ṣugbaa oun, o ni igi lẹyin ọgba oun ni. Igba kan naa wa ti Funkẹ dọgbọn fẹsun kan Falz pe o ti fẹẹ maa gbagbe ifẹ rẹ fun Jẹnifa o, o ni aaro rẹ maa n sọ oun.

Kehinde Oloyede
AbdulRassheed Bello (JJC Skillz)
Folarin Falana (Falz)
Funke ati Falz

Ẹ o tun ranti pe, bo tilẹ jẹ pe apọn ti ko tii laya ni Falz, adelebọ ni Funkẹ Akindele, ẹẹmeji lo ti ṣeyawo lọọdẹ ọkọ, akọkọ lọọdẹ ọkunrin oloṣelu ilu Eko nni, Adeọla Kẹhinde Oloyede, bo tilẹ jẹ pe irin-ajo naa ko tojọ ko toṣu to fi fori ṣanpọn. Lẹyin eyi lo fẹ Ọgbẹni Abdurasheed Bello, ti ọpọ mọ si JJC Skillz, onkọrin, onkọtan to maa n ṣeto lori tẹlifiṣan ni, ọdun meje ni wọn fi ṣe tọkọtaya, Ọlọrun si fi ibeji ta wọn lọrẹ, amọ akude de ba igbeyawo nigbẹyin. Atigba naa si ni Funkẹ ti n ṣe Iya n da’gbe, bo tilẹ jẹ pe o gbaju mọ iṣẹ tiata rẹ karakara, o si rọwọ mu gidi nidi awọn fiimu rẹ, owo gọbọi n wọle fun un.

Ṣa, awọn ololufẹ wọn ko yee beere pe ki lo n lọ laaarin Funkẹ ati Falz, wọn lawọn n reti idahun o.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search