AMVCA: Ṣọla Ṣobọwale, Kanayo Kanayo, Lateef Adedimeji ati Awọn Miiran Gba Ami-Ẹyẹ

Ẹsẹ ko gba ero ni gbọngan ayẹyẹ Eko Hotels l’aṣalẹ ana ti ayẹyẹ ami-ẹyẹ AMVCA ti waye nilu Eko.

Yatọ fun Gomina Babajide Sanwoolu ti ipinlẹ Eko, ọpọ awọn gbajumọ oṣere Nollywood ati amuludun lapapọ lo pejọ sibẹ fun eto ami-ẹyẹ AMVCA ẹlẹẹkejila iru rẹ.

Pataki ninu awọn to gba ami-ẹyẹ AMVCA tọdun yi ni awọn meji ti wọn fun ni ami-ẹyẹ ni abala agba-ọjẹ – Ṣọla Ṣobọwale ati Kanyo O. Kanayọ. Ti Kanayo sì fi oore-ọfẹ naa pe fun atunṣe si iṣoro ikorira ajeji (Xenophobia) to n lọ lọwọ ni orilẹ-ede South Africa.

Arẹwa oṣerebinrin, Linda Ejiofor lo gba ami ẹyẹ oṣerebinrin to dantọ julọ, ti Uzor Arukwe si gba fun abala ti obinrin. Ami-ẹyẹ dinima to dangajiya julọ ni ẹkun iwọ-oorun ilẹ adulawọ (West Africa) lo ja mọ sinima Liṣabi lati ọwọ Lateef Adedimeji ati aya rẹ Adebimpe Oyebade lọwọ. Lara wọn miiran to tun gba oríṣiríṣi ami-ẹyẹ ni Bucci Franklin, Omoni Oboli ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn irawọ olorin takasufe mẹta ọtọtọ, Fave; Buju BNXN; ati Tiwa Savage lo ṣere nibi ayẹyẹ naa.

Lara awọn oṣere jankan-jankan to peju ni Jọkẹ Silva; Ọdunlade Adekọla; Toyin Aimakhu Abraham Ajewole; Bisola Aiyeola; Fẹmi Adebayọ; Wumi Toriola; Stan Nze; Layi Wasabi ati bẹẹ bẹẹ lọ lo peju.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search