Eyi laṣiiri to fa ija laaarin Funkẹ Akindele ati Fathia Balogun

Ṣe Yoruba bọ, wọn ni ọrọ to ba ṣoju ilu ko farasin, ki i ṣe ọrọ bookẹlẹ mọ pe aarin awọn agba-ọjẹ oṣerebinrin onitiata meji yii, Funkẹ Akindele ati Fathia Balogun, to tun n jẹ Fathia Williams, ko gun, ija to foju hande lo n lọ laaarin wọn, ọrọ ọhun si ti kuro ni ọrọ ilu kan, o ti di eyi ti awọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ wọn n kọminu si, tawọn ololufẹ awọn mejeeji si n sọ oriṣiiriṣii ero ati ati ọrọ nipa rẹ.

Loootọ ni lọgbọ-lọgbọ to bẹ silẹ laaarin Funkẹ ati Fathia ko kọkọ foju hande, nitori awọn mejeeji kọkọ n woye bi ọrọ ọhun ṣe n lọ, wọn si n fi i ṣe iso inu ẹku, ti Yoruba n powe pe amumọra ni, afigba ti ina ija naa burẹkẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, iyẹn nnkan bii ọsẹ kan pere lẹyin ti Funkẹ Akindele ko fiimu rẹ tuntun, to pe akọle rẹ ni “Everybody Loves Jenifa” jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ, tilu-tifọn, ṣadeede ni Funkẹ fi ibinu gba ori ikanni Instagiraamu rẹ lọ lọjọ Mọnde ọhun, to si gbọn orukọ Fathia Balogun yọ kuro lara awọn ololufẹ rẹ, o ṣa agba oṣerebinrin naa ni kọkọrọ lẹsẹkẹsẹ, ko si sọ idi to fi ṣe bẹẹ fun ẹnikan.

Ohun to kọkọ ru awọn eeyan loju ninu igbesẹ ti Funkẹ Akindele gbe yii ni pe Fathia Balogun ti Funkẹ yọ bii ẹni yọ jiga danu lori ikanni rẹ yii wa lara awọn oṣere to kopa ninu fiimu tuntun rẹ ọhun, ọrẹ si lawọn mejeeji lati igba pipẹ sẹyin, bo tilẹ jẹ pe awọn asiko kan ti wa tẹlẹ ti aarin wọn ri bakan, iyẹn si ti kọja tipẹ.

Ninu iwadii ti ITAFAAJI ṣe, awọn to mọ bo ṣe n lọ fidi rẹ mulẹ pe iwa afẹjẹ-sinu-tutọ funfun jade ti Fathia Balogun hu si Funkẹ Akindele lori ipolongo ati ipolowo fiimu Everybody Loves Jenifa tuntun yii lo bi Funkẹ ninu, igba to si ro kinni ọhun titi, ti ko le mu un mọra mọ, lo ba kuku fi ọrọ ọhun ṣe ‘bi eera ba fi’ni pe igi, niṣe la a wọn ọn danu,’ eyi lo fi bulọọku Fathia lọgan, gẹgẹ bawọn eleebo ti n sọ.

Wọn ni latigba ti wọn ti ya fiimu naa tan, ti Funkẹ Akindele ti n rọ kuku-kẹkẹ lori ipolongo rẹ, tawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ naa ti n kọwọ ti i bii igba ẹkẹ ṣee kọwọ ti ile, niṣe ni Fathia Balogun dagunla si i, ko tiẹ ṣe bii ẹni ri i rara, bẹẹ ni ko ba a polowo fiimu naa lori ikanni rẹ, amọ o n polowo awọn fiimu mi tawọn onitiata ẹlẹgbẹ wọn ṣe lori ikanni tirẹ. Ere ni, awada ni, nigba ti ọrọ naa yoo burẹkẹ daadaa, ọjọ pe ti wọn yoo ṣafihan fiimu naa, ṣibaṣiba si ni ẹsẹ awọn eekan eekan oṣere atawọn ọjẹwẹwẹ onitiata pe si gbọngan iworan to wa ni Lẹkki, l’Ekoo, agaga awọn oṣere to kopa ninu fiimu tuntun ọhun, amọ ko si ẹni to gbọ ‘mo ko o’ Faith Balogun, ko wa, ko yọju, ko ranṣẹ, ko si ṣe bii ẹni pe oun tiẹ mọ ohun to n lọ. Eyi lo tubọ bu epo si inu to n bi ‘Sulia kẹn, Ayetoro kẹn’, gẹgẹ bii aṣa Funkẹ Akindele ninu fiimu rẹ atijọ.

Wọn ni eyi ti Fathia Balogun iba fi wa, niṣe lo gbaju mọ fiimu rẹ to n pò pọ̀ lọwọ, eyi to pe akọle rẹ ni “Ẹfunroye D Unicorn”, ṣe ko kuku si ẹni ti Ọlọrun ko ṣe fun.

Lọwọ keji ẹwẹ, awọn to sun mọ Fathia Balogun daadaa ni ẹni ti ko ba gbọ tẹnu ẹga ni i sọ pe ẹyẹ oko n pàátó, wọn ni Fathia ko kan ṣadeede dẹyẹ si Funkẹ lojiji bẹẹ, wọn ni inu rẹ ko dun si Funkẹ Akindele ni latari iwa ti wọn ni obinrin naa hu nigba ti Baba to bi Fathia lọmọ ku loṣu diẹ sẹyin, ti wọn si ṣayẹyẹ isinku rẹ gbaka-gbiyan. Wọn ni bi ọgọọrọ awọn onitiata atawọn ololufẹ Fathia Balogun ṣe ṣugbaa rẹ to lasiko ọhun, ti wọn duro ti i, ti wọn si pesẹ sibi ayẹyẹ ẹyẹ ikẹyin Oloogbe, niṣe ni Funkẹ kọ ipakọ si Fathia, ko yọju sibi inawo rẹ, bẹẹ ni ko ṣatilẹyin fun ọmọ olokuu ẹlẹgbẹ rẹ yii. Wọn ni eyi lo mu ki Fathia Balogun fi ọrọ ọhun ṣe oro too da mi ni mo da ọ ati pe bi eegun ba loun ko ri Jọntọ, Jọntọ naa aa sọ poun ko ri eegun ni, gẹgẹ bi owe Yoruba kan ṣe lọ.

Amọ ṣa o, ọrọ bi Funkẹ ṣe fibinu yọ Fathia danu yii ti de etiigbọ rẹ, oun naa si ti gba ori ikanni Instagiraamu rẹ lọ, laijafara loun naa gbọn Funkẹ Akindele yọ danu lori ikanni tirẹ, o ṣa a ni bulọkin, gẹgẹ bii aṣa awọn ọdọ iwoyi, ni tuu ba ge fọọ fawọn mejeeji.

Fathia tun gbe ọrọ kan sori ikanni rẹ ṣa o, ọpọ eeyan si sọ pe ko sẹni meji to n fi ọrọ ọhun pàrokò si ju Iya Ibeji, iyẹn Funkẹ Akindele lọ, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ rẹ. Fathia ni: “Ẹnikẹni to ba tilẹkun mọ mi lori ẹrọ ayelujara ko kuku le tilẹkun mọ mi lọdọ Ọlọrun Ọba o.”

Ọpọ awọn ololufẹ Funkẹ ati Fathia ni wọn ti n parọwa sawọn irawọ oṣerebinrin mejeeji yii pe ki wọn f’ọwọ wọ’nu, ki wọn f’iye de’nu gidigidi lori ọrọ yii, ki ọrọ to yẹ ki wọn yanju nitunbi inubi ma lọọ di yanpọnyanrin to maa da awuyewuye nla silẹ lagbo awọn oṣere tiata.

Bakan naa ni wọn ti n ke si awọn agbaagba ẹgbẹ tiata, awọn Baba Isalẹ ẹgbẹ atawọn alẹnulọrọ lawujọ lati maṣe wo Funkẹ Akindele ati Fathia niran o, wọn ni ki wọn tete ba wọn da si i, ki wọn si bu omi pa ina aawọ tuntun yii, ki ọrọ ọhun ma lọọ bẹyin yọ laipẹ.

Ohun ti yoo tun ṣẹlẹ lawọn eeyan n reti bayii.  

 

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search