Eyi nidi ti ija emi ati Lizzy Anjorin ko fi le pari laelae – Iyabọ Ojo

Ilumọ-ọn-ka oṣere-binrin to tọrọ da ṣaka lẹnu rẹ nni, Iyabọ Ojo, ti sọ pe bi ọta aye oun  ọrun o gbebọ kan ba wa toun atiẹ maa jọ na an tan bii owo titi ti Jesu maa fi pada de, ọta ọhun ko pe meji, Lizzy Anjọrin, oṣere-binrin onitiata ẹlẹgbẹ rẹ ni.

O ni ija oun ati obinrin arẹwa to tun ṣe okoowo aṣọ tita nni ko tii pari, ko si le pari laelae, ati pe ile-ẹjọ lawọn jọ maa fi ọdun 2025 yii paara, kootu lawọn jọ maa taku si titi ti idajọ ododo fi maa waye lori awọn ẹsun eke kan to fi kan oun.

Iyabọ Ojo
Biọla Adebayọ
Lizzy Anjọrin

Iyabọ Ojo sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lori eto ayelujara kan, Talk to B, eyi ti oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, Abiọla Adebayọ ṣatọkun rẹ lọsẹ akọkọ ninu oṣu Kinni ọdun 2025 yii.

Niṣe ni Iyabọ Ojo n tu bii ejo lasiko to n sọrọ naa, o si han gbangba pe ọrọ ija oun ati Lizzy yii mumu laya rẹ, nigba to ni:

“Oṣere-binrin onitiata ẹlẹgbẹ mi kan tiẹ fẹsun kan mi pe ọwọ mi o mọ lori iku Mohbad. Loootọ ko darukọ mi ni taarata o, amọ gbogbo bo ṣe n sọrọ to si n ṣapejuwe, ko sẹni ti ko mọ pe emi lo n ba wi. Tori ẹ ni mo ṣe pe e lẹjọ, Lizzy Anjọrin lẹni ti mo n sọ o, emi atiẹ si wa ni kootu titi doni.

“Amọ, gbangba ni mo ti n sọ ọ yii, mi o ni i gba ọrọ itunbi inubi kan. Rara ati rara ni. O si nidii ti mi o fi nii gba.”

“Loootọ ni adajọ yẹn gbiyanju pe ki ija pari, awọn eto si n lọ lọwọ lori ẹ, amọ a ṣi wa ni kootu. O yẹ ka pade ni ọjọ Kejila oṣu Kejila ọdun 2024 to kọja yii, amọ ko ṣee ṣe, tori emi o si nile. Kootu ṣẹṣẹ maa da ọjọ mi-in ti wọn ba fi ọrọ si ni. Ẹnikan si wa bii onilaja to n ṣiṣẹ lori pe ka yanju ọrọ naa nitunbi inubi.

“Amọ, gbangba ni mo ti n sọ ọ yii, mi o ni i gba ọrọ itunbi inubi kan. Rara ati rara ni. O si nidii ti mi o fi nii gba. Idi kan ni pe titi di ba a ṣe n sọ yii, ko tii jawọ ninu bibami lorukọ jẹ ati fifi ẹsun eke kan mi. Iyatọ wa laaarin keeyan fabuku kan-an-yan ati ki wọn fẹsun eke kanni, boya o darukọ o tabi ko darukọ.  Emi le darukọ ẹ daadaa tori emi o fẹsun eke kan an, mi o si ba a lorukọ jẹ, amọ oun o le darukọ mi tori o mọ pe irọ loun n pa mọ mi. Tori bẹẹ, teeyan ba n ba mi lorukọ jẹ, to n fẹsun ohun ti mi o ṣe kan mi, orukọ ti mo ti n ṣikẹ ẹ bọ lati ọpọ ọdun sẹyin, mi o le fọwọ lẹran lori iru nnkan bẹẹ.

“O ni emi ni mo n jẹ Gistlover. O lawọn ọmọ mi ni wọn n ṣe Gistlover. Wọn bi i leere pe ṣe emi lo n pe ni Ṣẹpẹtẹri, o ni emi kọ ẹnikan ni, wọn tun ni mo n fẹ Naira Marley, oṣere temi atiẹ ko jọ duro sọrọ nibikibi ri. Tori ẹ, ija emi ati Lizzy, ajaku akata ni, ko le pari titi ti Jesu maa fi de. Mi o ṣere, mi o si ṣawada rara. Ọdun 2025 ta a wa yii, a tun jọ maa ko si jalẹ ni, titi ti gbogbo ẹsun eke to n fi kan mi fi maa foju han nile-ẹjọ, mi o ni i jawọ o.”

“Tori ẹ, ija emi ati Lizzy, ajaku akata ni, ko le pari titi ti Jesu maa fi de. Mi o ṣere, mi o si ṣawada rara. Ọdun 2025 ta a wa yii, a tun jọ maa ko si jalẹ

Tẹẹ o ba gbagbe, ọjọ ti pẹ ti aawọ gbigbona janjan ti n lọ laaarin awọn oṣere-binrin alafẹ mejeeji. Ojoojumọ ni wọn n bu ara wọn labuuṣidii, ti wọn n sọko ọrọ si ara wọn, ti wọn si n fi epe kabiti kabiti ṣọwọ si ara wọn lori ẹrọ ayelujara. Igba to ya ni ọrọ naa di tile-ẹjọ, Iyabọ Ojo pe Lizzy lẹjọ, Lizzy naa si ni oun ko bẹru, gbogbo ere t’Iyabọ ba fẹẹ sa, ko niṣo. Bo tilẹ jẹ pe Adajọ-binrin kan to gbọ ẹsun awọn mejeeji lọdun 2024 parọwa si tọtun-un tosi pe agba obinrin ni wọn, ki wọn lọọ feegun otolo to ọrọ aarin ara wọn bo ṣe yẹ, sibẹ, ina ija naa kọ, ko ku, Iyabọ ni Lizzy ko yee bu oun, bẹẹ loun naa ko ni i fi i lọrun silẹ o. 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search