Funkẹ Akindele Wọ Toyin Aimakhu Ni’lẹ L’ode Iyabọ Ojo

N ṣe ni ori ikanni ayelujara gbogbo n gbona girigiri lati igba ti fọnran alawuyewuye kan ti ja’de nibi eto kiko sinima tuntun “the Return of Arinzo” ja’de lati ọwọ gbajumọ oṣere ati agb’erejade (producer) nni, Iyabọ Ojo.

Ninu fọnran to da wahala silẹ naa ni a ti ri gbajugbaja oṣere Toyin Aimakhu to n ki awọn eniyan to joko papọ yipo tabili kan nibi ode ariya naa. Lara awọn to joko yi tabili naa ka ni Iyabọ Ojo fun’ra rẹ, Mercy Aigbe to fi mọ Funkẹ Akindele ti ọpọ mọ si (Jennifer). Koko oun yo to di awuyewuye ni bi Funkẹ ṣe fi Toyin gun lagidi, ti ko si dahun ikini rẹ. Ṣe ninu fọnran naa ni Toyin ti bẹrẹ si ni ki ẹnikọọkan awọn gbajugbaja oṣerebinrin to joko yika tabili naa ṣugbọn Funkẹ ni ti ẹ ko ran Toyin ni’ṣẹ rara, n ṣe lo gboju s’oke, ti ko si fi aidunnu rẹ bo fun Toyin. Akoko naa dabi iyẹpẹrẹ fun to Toyin ṣugbọn to n naa ṣ’ara giri to si ka iṣẹlẹ naa s’ara.

Laarin bi onikaluku lori ayelujara ṣe n fi oju iwoye wọn le’lẹ, ti wọn si n gbe idajọ kalẹ lori iṣẹlẹ naa, ni awọn kan n gbiyanju lati wa idi pato ti Funkẹ yoo fi ṣe bẹ hu iwa si Toyin ni ita gbangba, awọn kan gbagbọ pe orogun owo lo n ṣe wọn, bẹẹ awọn kan pe iṣẹlẹ naa ko le yẹ lẹyin ọrọ kan ti gbajumọ adari ere, Kunle Afọlayan sọ lọjọsi nipa awọn to n pawo nla ni sinima ṣugbọn to jẹ pe owo taṣọrẹ lo n pada de ọwọ wọn nitori baranda ati ere ajẹju awọn onisinima.

L’aarin bi ọrọ yi ti n lọ, aworan atẹjade ọrọ Toyin l’ori ayelujara to n mẹnuba iṣẹlẹ naa ati bo ṣe bi oun ninu to, t’oun ti bo ti ṣe gba Funkẹ danu kuro (unfollow) l’oju opo ikanni Instagram rẹ ti ja’de botilẹjẹ o pada yọ atẹjade naa, amọ ṣa ti Funkẹ ko ti sọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ naa. L’ara awọn irawọ ogbontarigi oṣere to peju sibẹ ni, Fẹmi Adebayọ, Fausat Balogun (Madam Ṣajẹ), Ayọọla Kamọ State laarin awọn miran.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search