Òye-àtọwọ́dá: Òlàjú tàbí ìrégbè

Òye-àtọwọ́dá:
Òlàjú tàbí ìrégbè
Click Here
Artificial intelligence:
civilization or pointless
Click Here

Yorùbá  bọ̀ wọ́n pé, b’áyé bá ṣeun yí, ni ká mọ́ọ bá ayé yí, b’ìgbà bá ń yí, ká mọ́ọ bá’gbà yí ní ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé.
 A kò ṣàì mọ̀ pé, ojoojúmọ́ ni ìgbà ń yíi padà, tí ọ̀làjú sì ń fẹ’jú-kẹkẹ, èyí tó ti ń mú wa rí ìwúlò ìmọ̀-ẹ̀rọ ìgbàlódé tó tún pẹ̀lúu òye-àtọwọ́dá táa tún mọ̀ sí Artificial intelligence tàbí AI.
Léhìn ọ̀pọ̀ ìwádìí, a kò leè tọ́ka síi pé, iye òònkà báyìí ni àmúlò òye-àtọwọ́dá jẹ́ l’ágbàyé, torípé, àwọn iléeṣẹ oní-òye-àtọwọ́dá tí yóó fẹ́ẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin lóti wà lágbàyé lọ́wọ́lọ́wọ́, àtipé, orílè-èdè America, ló sì ń léwájú nínúu àwọn orílè-èdè, tí irúfẹ́ iléeṣẹ yìí pọ̀ sí jùlọ

   Ṣèwárii, òye-àtọwọ́dá yìí wà ní onírúurú, ó sì ní àkànṣe iṣẹ́ tí a ṣe-ẹ̀dáa wọn fún. Tí ẹ bá wo orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tó já fáfá yín, táa tún mọ̀ sí smartphones, a ti ṣe ẹ̀dáa òye-àtọwọ́dá tí ẹ leè mú-lò sòríi wọn.

  Bóyá, a fẹ́ fi kọ ìwé ni, tàbí a ní ohun kan tí a nílò ìlanilọ́yẹ̀ tàbí àlàyé fún, ìtàn ni, àwòrán, orin, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, a ti ní òye-àtọwọ́dá fún ìkòòkan wọn.
Bákanáà, àwọn ẹ̀rọ, aláṣìíkáyé, àwọn ìkànnì ìbáraẹnidọ́rẹ̀ẹ́, bíi facebook, X tóún jẹ́ twitter tẹ́lẹ̀, Snapchat, Instagram, Google, telegram, spotify, Youtube àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, niwọ́n ti ní àwọn abala tẹ́ẹ ti leè kàn sí òye-àtọwọ́dá tó wà lóríi wọn

  Ó tún yẹ kẹ́ẹ mọ̀ pé, a ti ní àwọn ẹ̀rọ olóye-àtọwọ́dá tí a kò leè mọ́ bá pàdé lóríi àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tó já fáfá, ìyẹn smartphones wa, àti èyí tí a ṣ’ẹ̀dá láti mú ayé rọrùn fún mùtúmùwà,

bíi ChatGPT, èyí tí ilèesẹ́ OpenAI dá sílẹ́, béè la ní Claude lát’ọwọ́ọ iléeṣẹ tóún jẹ́ Anthropic, àti LLaMA lat’ọwọ Meta, tòunti Gemini lat’ọwọ Google, a kò ní ṣaláì dárúkọ ọkọ̀ ayọkẹlẹ Tesla-autopilot, tóún lo òye-àtọwọ́dá  lojuu pópó, eyití iléeṣẹ tesla incorporated gbéjáde, béè la ní àwọn ẹ̀rọ táa ṣẹ̀da láti ṣe bí ènìyàn, èyí tí a ti ń múlò láwọn orile-èdè tó lajú dáadáa lágbayé

Sùgbón, ibití a fẹ́ yà sí gan ni, irú itú àti àrà tí àwọn èèyàn ti ń fi òye-àtọwọ́dá yìí ṣe
Lẹẹkan, a dárúkọ Ilèeṣẹ́ OpenAI, gégébí Olùdásílẹ̀ ẹ̀rọ ChatGPT yìí, èyí táa dásílẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwa táa bá nílò ẹ̀kọ́ lórí ohun kan tàbí òmííran, kódà, a leè bá èrò AI yìí takurọ̀sọ bíi pé à ń bá èèyàn bíi tiwa sọ̀rọ̀

  Béè la ni Gemini, ti iléeṣẹ Google dásílẹ̀, òhun tún lágbára pupọ̀ débii pé, a leè fi ṣe ìṣirò, a leè  fi túmọ̀ èdè kan sí òmíràn, a leè fi ṣe ìwádìí tó kún-kẹ́kẹ́, yàtọ̀ sí àwọn ìbéèrè pẹ́sẹ́pẹ́sẹ́ tí yóò fi ìdáhùn sí.

  Báwo gan ni èyí ṣe rí béè, àbí ìmọ̀-ẹ̀rọ a wa tún jẹ́ apidán ni? Rara o!

 Èèyàn ló wà nídìí orò t’ọ́rò fi ń ké o, béè, ìròmi tóún jó lórí omi, ẹni ń lùlùú fún-un ńbẹ nísàlẹ̀ odò, ìyẹn ni pé, àwọn èèyàn ló ṣèwádíí ìjìnlẹ̀, kó ìmọ̀ jọ, tí ojú òpóo AI yìí fi já geere, èyí tó fi mùú dà bíi pé, èèyàn là ń báá sọ̀rọ̀, àti bíi pé ẹ̀dá èèyàn ló wà nínú àwọn ẹ̀rọ olóye-àtọwọ́dá yìí.

Bótilẹ̀jépé a ṣ’èdá àwọn ẹ̀rọ yìí láti máà bá’wa ronú, tàbí mú isé rọrùn fún wa,

    ó wá féé dà bíi pé, àwọn èèyàn kò mọ èrọ yìí lò bóti yẹ, kódà, àpára ni elomiiran ń fi ChatGPT yìí dá

Ṣèwárii, ohun kan ló b’eyín ajá jẹ́ o
   AI ṣì ní ibití ó kù sí, èyí tí a kò leè tọ́ka sí tán táa bá ni ká tẹnu bọ̀’ròyìn,
     Sugbon, eyí tí àwọn èèyàn sáábà mọ́ ń tọ́ka sí jùlọ ni bí, AI kò tiṣe ní ìdáhùn tó bá ìrírí tó pójú-òṣùnwọ̀n pẹ̀lúu ìròrí ẹ̀dá mu.

  Fún àpẹẹrẹ Tí a bá fi AI tún àwòrán kan ṣe, tí a wáa gbé àwòrán tí AI gbéjáde àti èyítí tó jẹ́ ògidì àwòrán sí ẹ̀gbẹ́ araa wọn, gbangba-gbàngbà ló mọ́ ń hàn pé, àgbéjáde AI kún fún àmọ̀já tabí kání kò ní sọ ojú abẹńkòo fún ẹni tó bá múulò,

 fún àpẹẹrẹ, ẹnìkan, ti jẹ́rìísíi wípé, ẹrọ AI kan tí òhun lò láti fi kọ iṣẹ́ àkànṣe òhun kan, ló ṣe àkóbá fún òhun tí òhun kò fi leè wí àwíjàre tó yẹ nígbàtí òhun dé iwájú ògá òhun, torípé àwọn ìwádìí AI tí òhun lò, ni kò bá ti orílè èdè tí óhun wà mu, èyí sì mú kí òhun kó pàdánù àwọn iye owó kan nígbànáà.

   Èwè, táa bá fi ohùn AI ká ọ̀rọ̀ sílẹ̀, táa  sí gbọ́ọ l’ẹ́ẹ̀kanáà pẹ̀lú èyí tójẹ́ ti ẹ̀dá ènìyàn, a yóò rí ìyàtọ̀ gédégbé tó wà láàrin wọn, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ ló

èyí kìí ṣe láti fi ṣèbàjẹ́ẹ afojúsùn  tí àwọn Olùdásílẹ̀ ẹ̀rọ olóye-àtọwọ́dá yìí ni o, béè ni a kò sè èyí láti fi tẹ́nbẹ́lúu isé takuntakun tíwọ́n ń ṣe láti fi mú kí ìgbésí ayé kó rorùn fún àwùjọ

  A kàn ń fi èyí wòye lápá ibẹ̀un ni
      Àmọ́ṣhá, ó yẹ ká bi ara wá leeré pé, ṣe èrò Al kò níi sọ iran ọmọnìyàn di ọ̀lẹ bí?
Ńjẹ́ kò tún tunmo sí pé, àwọn ohun elo yìí yóò rọ́pò eda eniyan lawon iléeṣẹ ìgbàlódé tó bá tún dide lójó iwájú.
Àtipé, se àwọn onírúurú ayípadà àti àtúnṣe tóún bá àwọn èrò yìí leè mú wọn ṣe gbogbo ohun tí èniyàn leè ṣe, Lai kù síbìkan bí?

Tòó…
 Ìyẹn di lójó iwájú, nígbàtí a bá tún rí àrà mìíràn tí èrọ náà leè dá.

Start typing and press Enter to search