Idaamu Portable: “Mi o lọọ kọrin ni London mọ, adura ni mo nilo!”

Portable to maa n daṣa 'wahala, wahala' wọ wahala gidi lọdọ ijọba

Asiko yii kii ṣe eyi to rọgbọ fun gbajumọ onkọrin taka-sufee tawọn ọdọ fẹran nni, Habeeb Okikiọla ọmọ Ọlalọmi, ti ọpọ eeyan mọ si Portable olorin zah zuuh zeh, ko si ẹrin lẹnu onkọrin naa rara, o si han gbangba pe o ni idaamu ọkan, pẹlu bo ṣe rawọ ẹbẹ sawọn ololufẹ rẹ pe ki wọn wọle adura fun oun ati mọlẹbi oun, o loun nilo atilẹyin wọn gidigidi, ki awọn ọta alẹnimadẹyin le jẹ koun ri imu mi.

Koda nibi tọrọ naa ka ọdọmọkunrin naa lara de, Portable ni oun ti wọgile irinajo pataki kan to yẹ koun lọ lati lọọ fi ere da awọn ololufẹ oun lara ya niluu Lọndọnu, lorileede United Kingdom lọhun-un, o loun o lọ mọ, tori eeyan ki i ru ẹran erin sori ko tun maa fẹsẹ wa iho irẹ, ọrọ ode ere kọ lo ba oun lasiko yii, boun ṣe fẹẹ daabo bo idile oun, okoowo oun ati dukia oun lo mumu laya oun bayii.

Ẹ o ranti pe laaarin ọsẹ to kọja yii ni ijọba ipinlẹ Ogun lọọ lẹ iwe “kuro lori ilẹ ijọba” mọ ile kan ti ọkunrin to fẹran lati maa daṣa wahala, wahala, wahala yii n kọ lọwọ, wọn ni ibi to kọle naa si ko bofin mu, ati pe ko gba iwe-aṣẹ to yẹ lọdọ ijọba ko too bẹrẹ si i mọ ile, latari eyi, wọn ti ile naa pa, wọn si ami ‘a maa wo ile yii laipẹ’ sibẹ.

Bakan naa ni wọn tun fi pampẹ ofin gbe awọn kọsitọma ati oṣiṣẹ rẹ kan ti ọwọ awọn agbofinro tẹ lasiko naa.

Odogwu bar

Latigba ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ ni Portable ti kegbajare si Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ati awọn alaṣẹ ijọba gbogbo pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn maṣe wo ile mọ oun lori, o ni kijọba wo ti pe ọpọ iranlọwọ loun ti ṣe fun wọn, oun loun ṣe ina si opopona kaakiri adugbo naa, toun si fowo ara oun tun ọna ṣe, bẹẹ ojuṣe ijọba ni gbogbo eyi.

Amọ ko jọ pe ẹbẹ Portable wọ ijọba leti, tori ijọba ipinlẹ Ogun ti fesi pe ki i ṣe ile ti Portable n kọ lọwọ nikan lo lodi sofin, wọn ni Odogwu Bar rẹ, iyẹn ile itaja to ti n kọrin, eyi to wa lagbegbe Ilogbo, nitosi Sango Ọta, ko bofin mu, wọn ni gbogbo dukia wọnyi yoo gbalejo katakata laipẹ, wọn yoo wo wọn palẹ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2025 yii ni Portable gba ori ẹrọ ayelujara rẹ lọ, lori ikanni Instagiiraamu lati fi ẹdun ọkan ati irawọ ẹbẹ rẹ han. Ṣe Oloogbe adẹrin-in poṣonu nni, Gbenga Adeboye ti sọ ninu awo rẹ kan pe ‘bọwọ kilango (kill-and-go) ba tẹ alagidi, íi jẹntu (gentle) kẹyin ni, ọrọ ti ọkunrin to tun maa n pe ara rẹ ni Idaamu Adugbo, Ika of Africa yii kọ sori intanẹẹti ṣeeyan laaanu gidigidi, o ni:

“Zazuu zeh. Mo ni lati kọkọ daabo bo mọlẹbi mi ati dukia mi na o. Ilu London, aa maa ri’ra lọjọ iwaju, eni kọ leeyan ti n rinrin-ajo lati wa owo lọ jare. Orin ni iṣẹ mi, ti ẹmi ba ṣi wa, ko si ibi teeyan ko le de.

“Ẹyin fansi mi, ko sohun meji ti mo nilo lasiko yii ju adura ati atilẹyin yin lọ o.

“Amọ mo gba pe Ọlọrun wa, eeyan ko dabi Ọlọrun, ati pe adun lo n gbẹyin ewuro.”

Ọna to bajẹ
Sẹnetọ Yayi

Tẹẹ o ba gbagbe, asiko kan ninu ọdun 2024 to kọja yii ni onkọrin tẹnu rẹ mu bii abẹfẹlẹ yii sọrọ ṣakaṣaka si Gomina Dapọ Abiọdun ati iṣakoso rẹ nipinlẹ Ogun, nigba ti ọkọ Range Rover rẹ ko sinu ẹrọfọ lagbegbe naa, latari ọna ti ko daa, Portable ni ki Gomina fipo silẹ, ko jẹ ki Yayi, iyẹn Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla bọ sibẹ, tori Yayi lo le ṣe e.

Bo tilẹ jẹ pe Portable tun pada gboṣuba fun Gomina Abiọdun lẹyin naa nigba to ṣabẹwo si ọna Atan si Agbara tijọba n ṣatunṣe rẹ, sibẹ ọpọ lara awọn ololufẹ onkọrin lo ti n sọ pe ẹsan ọrọkọrọ ati iwa aikora-ẹni-nijaanu rẹ lo fa gbogbo laasigbo to de ba a yii.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search