Ni bi akanṣe eto idije aree bọọlu to ma n waye lọdọọdun lat’ọwọ ajọ ẹlẹyinju-aanu Lydia-Wilson Foundation fawọn ogo wẹẹrẹ ni ipinlẹ Eko lojuna ati mu agbega ati idagbasoke ba wọn, ti ọdun 2026 to wa s’opin laipẹ yii pẹlu ifẹsẹwọnsẹ ni ipele aṣekagba to waye l’ọjọ Abamẹta Satide (9th May, 2026) to kọja laarin ikọ Football Ambassadors lati Ebute Metta to gbe igba oroke pẹlu fifi agba han ikọ 11 Stars pẹlu ami ayo mẹta si meji nipasẹ goli-wo’mi-kin-gba (penalt shootout). N ṣe ni ariwo sọ lala ni papa iṣere ile-ẹkọ alakọbere St. Peter to wa ni Ebute Metta, Eko ni ibi ti ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba naa ti waye.
Lopin idije naa, ikọ Football Ambassadors gbe ife ẹyẹ pẹlu ami wura, ti ikọ 11 Stars si gba ami fadaka. Yatọ fun eyi, awọn akopa mẹjọ to fakọyọ julọ ninu idije naa ninu eyi ti mẹta jẹ abo ninu wọn lo tẹwọ gba ẹbun pataki ati ẹbun owo kiṣi (cash prize).
Ko tan sibẹ, yatọ fun pe idije naa jẹ ọna lati fi ẹbun awọn ọjọ-ọla orilẹ-ede Naijiria han, ajọ Lydia-Wilson Foundation tun ṣe eto anawọsi fun awọn opo yika orilẹ-ede Naijiria, ninu eyi awọn opo to le ni ọgọrun kan ti jẹ anfani rẹ.
Ninu ọrọ Ọgbẹni Wilson Balogun to wa ni ikalẹ nibi eto naa, to jẹ ọkan ninu awọn Oludasilẹ ajọ naa pẹlu aya rẹ, Abilekọ Lydia Wilson-Balogun to fi Ilẹ Ọba ni orilẹ-ede United Kingdom ṣe ibugbe. O ṣalaye pe lati ọdun 2018 ti ajọ naa ti bẹrẹ lo ti n lo ere idaraya lati mu idagbasoke wọlu ati iranlọwọ fawọn ogo wẹẹrẹ. Ati pe, ajọ naa n ṣe iṣẹ takuntakun lati mu ki awujọ tunbọ dara si paapaa julọ awọn ti ko rọwọ họri to nnkan nipasẹ ere idaraya, eto ẹkọ, ironilagbara, ati awọn eto iranwọ loriṣiriṣi.
Siwaju si, o pe fun ikunlọwọ ati aduroti lati ọdọ awọn ẹni ọrọ kan gbogbo bi ijọba, ẹka aladani, awọn ajọ onidagbasoke, at’awọn ẹlẹyinju-aanu miiran lati tunbọ maa tun ilu ṣe fun igbayegbadun kaluku ati idagbasoke to ṣe san-an.
Ẹwẹ, Wilson lu ile-iṣẹ Westdyke, Scotland, UK lọgọ ẹnu fun ipese awọn ẹwu igbabọọlu (jersey). Bẹẹ si ni eto jijẹ mimu fawọn agbabọọlu, awọn akopa to fi mọ awọn ti ko rọwọ họri ni itosi naa ko gbẹyin.