Lọjọ iṣile ati ayẹyẹ ọjọọbi, Obesere sọrọ igbesi aye ẹ
Gbajúgbajà onkọrin Fuji nni, Abass Akande, ti ọpọ eeyan mọ si Òbésèré Ọmọ Rápálá, ti sọ pe oun ko ni nnkan kan to jọ bi àbámọ̀ ninu igbesi aye oun, ko si si ọrọ ‘a n geka jẹ’ nibẹ pẹlu.
Laipẹ yii ni Obesere sọrọ ọhun nibi ifọrọwanilẹnuwo kan tawọn oniroyin ṣe fun un, ni isopo pẹlu ayẹyẹ ọjọ-ibi ọgọta (60) ọdun rẹ loke eepẹ, eyi ti ọgọrọ awọn ololufẹ rẹ ba a dawọ idunnu le lori.
Lasiko ayẹyẹ oni-beji ọhun ni Abasido, gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ lasiko to ba n kọrin, tun ṣi awọn ile mẹfa ọtọọtọ to ṣẹṣẹ kọ pari, o loun ra awọn ile naa ni, o si fi ọkan ninu rẹ tọrẹ fun ọmọọṣẹ rẹ kan.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo naa, o sọ ọ di mimọ pe ko si ohun to jọ abamọ ninu ọrọ oun nitori àkọọ́lẹ̀ Ọlọrun ti duro lori gbogbo ẹda.
Ọmọ Rapala ni: “Ko si nnkan ti mo ro pe ka ni mo ti mọ ni, boya ọna ọtọ ni n ba gbe e gba. Eto Ọlọrun Ọba ni gbogbo ẹ, mi o si kabaamọ ohunkohun rara. Mo gbagbọ pe ibi giga ni mo lọ, koda mi o tii bẹrẹ rara, mo ṣẹṣẹ n m’ẹyẹ bọ lapo ni.”
Nigba ti wọn bi i leere awọn aṣeyọri ati nnkan aritọkasi to gbe ṣe nidii iṣẹ orin rẹ, o fesi pe: “Awọn aṣeyọri mi pọ o, aa, mi o tiẹ le mẹnuba wọn tan! Ṣe ti awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ta mi lọrẹ, to si tun ran mi lọwọ ti mo fi le ran wọn nileewe niluu oyinbo ni ki n sọ ni? Abi ti emi gan-an alara, ti Ọlọrun fun lanfaani lati di ọmọ oniluu niluu oyinbo, abi ti awọn ile loriṣiiriṣii ati okoowo ti Ọlọrun fun mi ni ki n ka ni? Meloo ni ka wi, meloo ni ka sọ, wọn pọ!”
Obesere fi kun un pe itan igbesi aye oun jẹ eyi t’awọn to n bọ lẹyin gbọdọ fi ṣe awokọṣe nitori ọgbọn ọlọgbọn la fi n ṣ’ọgbọn. Fun idi eyi, oun ti ni in lọkan lati kọ itan igbe aye oun sinu iwe ati sori fọnran.
Ọmọ bibi ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ, ni Obesere, ogunjọ oṣu Kinni, ọdun 1965 ni wọn bi i. Bo tilẹ jẹ pe o ti n kọrin Fuji labẹlẹ diẹ-diẹ, ọdun 1981 lawọn eeyan n mọ ọn, ki irawọ rẹ too bu yọ nidii iṣẹ naa, latari iṣọwọ kọrin Fuji rẹ to yatọ, o maa n lo awọn akanlo ede, fidi ọrọ ibalopọ daṣa, lilo afiwe ẹlẹlọọ, ati oriṣii orin ẹfẹ kan ti wọn n pe ni “Ṣajẹ.”
Ilumọ-ọn-ka ni oṣere naa, o si ti gbe orin Fuji rẹ kaakiri awọn orileede agbaye. Lara awo orin rẹ tawọn eeyan gbajumọ daadaa ni Asakasa, O.B.T.K., Mr. Teacher, Ọmọrapala Overthrow, Egungun Be Careful, Old Skool Lapẹ, Okokoriko, Ọbaadan, Effissy ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Yatọ si orukọ inagijẹ Obesere ati Ọmọrapala tawọn eeyan mọ ọn si, Abass Akande tun lawọn orukọ mi-in bii Sidophobia, Papa Tọsibẹ, Ọba Alaṣakaṣa ati bẹẹ bẹẹ lọ.