Ọmọwunmi, Iyawo Mohbad ti sọrọ jade lori iku ọkọ rẹ o!

Eyi ni igba akọkọ ti Ọmọwunmi Alọba, Iyawo Mohbad yoo ba oniroyin sọrọ lori iku ọkọ rẹ

Ṣe ẹ ranti Ọmọwumi Alọba, iyawo gbajugbaja ọdọmọde olorin taka-sufee t’okiki iku rẹ kan l’ọdun 2023 nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad?
Lẹyin ọpọ oṣu ti iyawo Oloogbe yii ti fẹnu-mọ́nu, ti ko sọ ohunkohun nipa iku ọkọ rẹ, lai ka ti ọgọọrọ ẹsun oriṣiiriṣii ti wọn n fi kan an lọtun-un losi si, Wumi ti jade ba oniroyin sọrọ bayii fun igba akọkọ lati ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ti iku ojiji ti da ẹmi ọkọ rẹ legbodo, 

ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27). Wumi ti jade ba oniroyin sọrọ bayii fun igba akọkọ lati ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ti iku ojiji ti da ẹmi ọkọ rẹ legbodo, ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27).

Ori eto kan to jẹ elede Gẹẹsi lori amohun-maworan ẹrọ ayelujara lo ti tẹnu bọrọ laaarin ọsẹ ta a wa yii, nipa ohun to ṣẹlẹ ati oniruuru iriri to n gbomi loju ẹni, toun ti la kọja.

Ẹ o ranti pe ọpọ awọn eeyan lo gbagbọ pe ejo ọdọmọbinrin naa lọwọ ninu lori iku ọkọ rẹ, wọn ni ọwọ rẹ ko mọ nipa bi Mohbad ṣe ku lábàadì, ati pe ọpọ awọn ootọ ọrọ to fara sin lo wa l’ódò ikùn opó yii, to yẹ ko sọ faye gbọ, amọ ti ko sọ, lai fi ti igbiyanju ijọba ati t’awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan kọọkan to gba’rata lati tu’ṣu de’salẹ ikoko lori iku ohun pè.

Nigba to n dahun ibeere ti wọn bi i lasiko ifọrọwanilẹnuwo naa, Ọmọwumi ni oun ati ikoko ọmọ oṣu marun ti oun bi fun Mohbad lawọn f’oju wina idunkoko to lagbara latọdọ awọn alajọṣe tẹlẹri ọkọ oun, lara wọn ni Ọga Mohbad tẹlẹ, toun naa n kọrin hipọọpu tàwọn ọdọ fẹran, Ọgbẹni Abdulazeez Adesina Fáṣọlá ti wọn n pe ni Naira Marley, ati gbajumọ alafẹ ori ayelujara kan, Ọgbẹni Samson Erinfọlami Balogun ti ọpọ mọ si Sam Larry, ti Ọmọwumi fẹsun kan wipe wọn dun mọhuru-mọhuru mọ ọkọ rẹ d’oju iku.

Bákan naa ni iyawo Oloogbe tun fẹsun kan baba ọkọ rẹ, Alagba Joseph Alọba, o ni baba naa fi oju oun han mabo pẹlu bo ti ṣe n fẹ lati jẹ gaba lori awọn dukia ti ọmọ rẹ fi silẹ, to si tun fẹsun kan Liam, ọmọ-ọmọ rẹ pe oun fura si i pe ki i ṣe ojulowo ọmọ ọkọ. Sibẹ, Ọmọwumi ni ohun ko ni ẹbọ l’ẹru rara.

Ko tan sibẹ o, aya Mohbad tun ṣalaye pe loorekoore ni awọn kan lori ayelujara maa n wa f’ẹnu ṣaata oun, eyi si jẹ ọgbẹ ọkan nla fun oun, tori bẹẹ loun ṣe kegbajare dipo ki oun dakẹ ku.

Obinrin yi sọrọ kan ẹkun pẹlu bo ṣe ni ẹẹmeji ọtọtọ ni wọn ti t’ọwọ bọ oputu ara oloogbe lojuna ati ṣe iwadi ati awari okunfa iku rẹ, a mọ ṣa ti ko tii si esi taara ati idajọ to f’ẹsẹ mu’lẹ lori iku to pa ọdọmọde Olorin naa.

Awọn eeyan ti wọn wo fidio ifọrọwerọ yii ti n fesi si ohun ti Ọmọwunmi Alọba sọ yii, oju ọtọọtọ si ni wọn fi wo ọrọ naa.
Ọpọ lara wọn ni wọn sọ pe ohun t’awọn fẹ ki Wumi sọrọ le lori kọ lo n sọ, ohun to mọ nipa iku Mohbad, ọrọ ija oun ati Oloogbe ati otitọ ohun to ṣẹlẹ ni afẹmọjumọ ọjọ ti Mohbad mi eemi ikẹyin l’awọn fẹẹ gbọ lẹnu rẹ, amọ ọtọ ni ibi to n sọrọ lọ.

Bẹẹ l’awọn mi-in n fesi pe ki Ọmọwunmi lọọ ṣàlàyé ara rẹ fawọn agbofinro, ko si jẹ k’ayé mọ ootọ l’awọn fẹ.
Sibẹ, awọn kan kaaanu Iya Liam, wọn ni ki wọn fi ọmọbinrin naa lọrun silẹ, nitori ohun to pamọ, oju Oluwa lo to o, ati pe gbogbo ohun to ṣi ṣokunkun ni imọlẹ yoo tan si, to ba ya.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search