Ni bayii, bi ko ba si ayipada ninu ọrọ gbajugbaja oniṣowo agbaye nni, Alaaji Aliko Dangote, ko ni i pẹ, ko ni i jinna ti ipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Ondo yoo fi gbalejo awọn ileeṣẹ nla-nla ti yoo gbalẹ rẹpẹtẹ, eyi ti ọkunrin naa loun ti pinnu lati kọ si awọn agbegbe kan ni ipinlẹ mejeeji.
Ọrọ yii jẹ jade ninu ijiroro kan to waye lasiko abẹwo ‘ẹ n lẹ nbẹun o’ eyi ti Dangote ṣe si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lọfiisi rẹ to wa l’Oke-Mọsan, niluu Abẹokuta, olu-ilu ipinlẹ Ogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2025 yii.
Koko abẹwo Dangote, to jẹ Ọga agba patapata fun ileeṣẹ Dangote (Dangote Group) ni lati dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ogun, fun atilẹyin rẹ lori awọn ileeṣẹ to da silẹ nipinlẹ naa.
Dangote ni ijọba to wa nipo ṣaaju ti Dapọ, iyẹn iṣakoso Sẹnetọ Ibikunle Amosun, foju oun ri mabo, o ni ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn lọọ wo ileeṣẹ simẹti tuntun kan toun n kọ si agbegbe Itori, nijọba ibilẹ Ewekoro, lasiko ọhun danu, amọ ni bayii, oun dupẹ pe Gomina Abiọdun fọwọ sowọ pọ pẹlu oun, iṣẹ si ti n lọ ni rẹbutu lagbegbe naa bayii.
O fikun un pe nigba ti ileeṣẹ simẹnti naa ba bẹrẹ iṣẹ, o kere tan, lọdun kan, aropọ simẹnti miliọnu mejidinlogun tọọnu ni wọn yoo maa pese nipinlẹ Ogun nikan.
Lẹyin eyi ni Dangote tun mẹnu ba a pe boun ṣe n ṣiṣẹ lori ti ileeṣẹ simẹnti tuntun yii, bẹẹ ni idasilẹ aragba-yamu-yamu ebute tawọn ọkọ oju omi yoo ti maa gbera tabi fabọ si yoo bẹrẹ ni agbegbe Olokola, ti wọn n pe ni Olokola Free Trade Zone tẹlẹri, laipẹ jọjọ, gẹgẹ bo ṣe n gba a lero. Agbegbe yii wa lẹnu aala ipinlẹ Ogun ati Ondo, nijọba ibilẹ Waterside ati Igbọkọda.
O ni ebute nla toun fẹẹ kọ yii ni yoo jẹ eyi to gbooro julọ, ti yoo si fakiki julọ nilẹ Africa toun ba kọ ọ tan.
Lasiko to n fesi fun alejo rẹ, Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun sọ pe inu oun dun gidigidi si awọn igbesẹ ti Dangote pinnu lati gbe wọnyi, o ni idasilẹ ileeṣẹ naa yoo tubọ mu ki eto ọrọ aje rugọgọ si i, bẹẹ lo fikun un pe ijọba oun ti ṣetan lati ṣe atilẹyin to gbamuṣe fun Dangote, lori ọrọ ilẹ, ofin ati ipese nnkan amayedẹrun ti yoo mu ki idasilẹ ileeṣẹ naa tubọ yara kankan, nitori oun gbagbọ pe oore nla ni yoo jẹ fun ipinlẹ Ogun atawọn olugbe rẹ.