Ọmọ Ọdun Mẹwa Lo Ru’gba L’Ọṣun-Oṣogbo, Ẹ Wa Gbọ Bo Ti Jẹ Gan-an

Ọdun Ọṣun-Oṣogbo to ma n wa’ye ni nnkan oṣu kẹjọ (August) ọdọdun, ti ọdun 2026 lo ko l’oni ọjọ keje, oṣu kẹjọ. Ọdun Ọṣun-Oṣogbo ni’pinlẹ Ọṣun jẹ eyi to gbajugbaja kaari aye, koda ti ajọ UNICEF gan-an ya a ṣ’ọtọ nitori ojubọ Ọṣun-Oṣogbo, iyẹn ‘Ọṣun-Oṣogbo Groove’ to jẹ ọkan ninu awọn ibudo aṣa kaakiri agbaye ti ajọ UNICEF ya ṣ’ọtọ pe o ṣe iyebiye.

Ọdun Ọṣun-Oṣogbo ko ṣẹṣẹ bẹrẹ rara, ọdun naa ti le ni ẹgbẹta ọdun iyẹn (over 600 years). Awọn eniyan lati itosi ati ọna jinjin kaariaye lo si ma n pe jọ lati ṣe ọdun aṣa ibilẹ naa. Ninu wọn ni awọn ololufẹ aṣa ati iṣẹ ilẹ Yoruba; awọn agb’aṣaga; awọn oniṣẹ-iwadii; awọn arinrin-ajo-afẹ; awọn to n fẹ iwosan abi wa tọrọ oore abi ọọrẹ l’ọwọ Oore Yeye Ọsun l’aarin oniruuru awọn eniyan miiran.

Botilẹjẹ pe ọdun Ọṣun-Oṣogbo kii ṣe ọdun ọlọjọ kan taara nitori lati bi ọsẹ kan siwaju ni oriṣiriṣi awọn eto bii titan ina ‘Atupa Olojumẹrindinlogun’; iwọ popo ati bẹẹ bẹẹ lọ a ti bẹrẹ ṣugbọn ọjọ ti arugba yoo gbe igba Ọṣun lọ pẹlu awọn ero lẹyin lọ si ojubọ Ọṣun-Oṣogbo gan-an ni ọjọ nla, to jẹ odu ibẹ.

Omidan ti ko mọ ọkunrin ri, ti ibalẹ rẹ n bẹ ni sẹpẹ ni yoo ru igba yii pẹlu ti’lu-ti’fọn lẹyin rẹ, bẹẹ ni iwure naa yoo ma tẹle fun kabiesi Ataoja ilu Oṣogbo; gbogbo ilu Oṣogbo lapapọ ati gbogbo awọn olukopa.

L’ọdun yii, ọmọ kerekere ọmọ ọdun mẹwaa ti orukọ rẹ n jẹ Ọmọbabinrin Alimot Moradekẹ Ajọkẹ Ọṣunbunmi lo ru igba Ọṣun. Oṣu kẹta ọdun 2025 ni wọn fi ‘Ifa’ yan ọmọ naa. Ọmọ yi kanna lo jẹ arugba l’ọdun 2025 to lọ latari pe arugba tanaa Ọmọbabinrin Ọṣuntomi Ẹwatomi ti fi adagba igba riru rọ lati re ile ọkọ lẹyin ọdun mejila to ti jẹ arugba l’ọdun Ọṣun-Oṣogbo.

Ọmọbabinrin Ọṣuntomi to jẹ’Arugba’ tuntun ni ko lee gbe igba naa l’ọdun to lọ nitori ọjọ-ori rẹ, l’eyi to fa bi ‘Babalooṣa’ ti ran l’ẹru naa, t’oun si le’waju. Amọ ṣa, l’ọdun yii, arugba yii gan-an lo gbe igba ru, to tunmọ si pe gbogbo eto to yẹ ni wọn ti ṣe fun ọmọ naa.

Botilẹjẹ pe ọdun ti gori ọdun ti ọdun yii ti n bẹ, amọ ṣa aṣa olaju ko pa ọdun yii rẹ bi ko ṣe pe o tun p’okiki rẹ si ni.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search