Taye Currency jẹwọ: Miliọnu mẹwaa naira ni CBEX ko lọ lọwọ mi!

Ọjọ kinni, oṣu kẹrin, iyẹn April 1, ni mo ko owo mi lọọ ba CBEX, owo ti mo ti n da pamọ sọdọ awọn abanigbofo (insurance) mi,  miliọnu mẹwaa naira, tẹn miliọnu ni mo ko wọnu CBEX, niṣe lo ja sina. Gbogbo ẹyin tẹẹ tan mi wọnu CBEX, ẹ o nii ṣoriire o. Bẹẹ ba kuu’re, ẹ o nii sun ire.”

Eyi lawọn epe kabiti kabiti to n jabọ lẹnu gbajumọ onkọrin Fuji to filuu Ibadan ṣe ibugbe nni, Alaaji Taye Adebisi ti ọpọ eeyan mọ si Taye Currency, latari bo ṣe padanu ẹgbẹlẹmuku owo sinu okoowo sogun-dogoji ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni CBEX, eyi to foriṣanpọn nibẹrẹ ọsẹ taa wa yii.

Ninu fọran fidio kan ti Taye Currency gbe soju opo ayelujara, o ṣalaye pe lọjọ kinni oṣu Kẹrin ta a wa yii, Sodiq, iyẹn ọkan lara awọn ọmọọṣẹ rẹ ati Lateef to jẹ maneja rẹ, waa ba oun nile, pẹlu Alaba, ọmọọṣẹ rẹ mi-in, ati ẹnikan to ṣe ikẹrin wọn.

Alaba yẹn, 1.2 miliọnu to ji loju agbo ere loun ko sinu okoowo CBEX, Bọọda Muka naa ko ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) owo iṣẹ rẹ si i, o fi rẹjista si CBEX. Ṣẹẹ ri, bi Lateef ṣe ṣalaye pe oun fi tuu ọndirẹdi taosan, iyẹn ẹgbẹrun lọna igba naira ṣe okoowo na, toun si ri ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (600,000) gba pada lo wu mi lori, lemi naa ba sare lọọ gba owo inṣọransi mi, mo rọ ọ da si i, lo ba lana.”

Taye Currency ni ere ni oun kọkọ pe e nigba ti olobo ta oun pe nnkan kan ti n ṣẹlẹ si ikanni CBEX lori ẹrọ ayelujara, ti wọn lawọn eeyan ko ri owo gba jade nibẹ mọ. O loun kọkọ sọ pe ko jẹ jẹ bẹẹ, afi bi ọrọ naa ṣe ja si ootọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹrin ọdun 2025 yii, ti okiki kan pe CBEX ti lana, o ti rọ ẹgbẹlẹmuku owo awọn to dokoowo pẹlu rẹ mi bii kalokalo.

Bi ọrọ naa ṣe dun Taye Currency to, niṣe lo n ṣe epe ọlọkan-o-jọkan ninu fidio naa, bo ṣe n fi epe ranṣẹ sawọn ọmọọṣẹ rẹ to lawọn ni wọn tan oun wọnu okoowo CBEX, bẹẹ lo n ṣepe buruku buruku fawọn to da sogun-dogoji CBEX silẹ.

Tẹẹ o ba gbagbe, titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn eeyan ti okoowo CBEX yii sọ di ẹdun arinlẹ ṣi n keroora lori adanu ati ijakulẹ ti kinni naa fa fun wọn. Oriṣiiriṣii fidio ati ọrọ lori ẹrọ ayelujara lo ṣafihan ọgbẹ ọkan awọn to padanu owo wọn, bi awọn kan ṣe n sunkun yọbọ,  bẹẹ lawọn mi-in n mi imi-ẹdun gidigidi.

Lọjọ Mọnde ọhun, awọn ọmọ ganfe, atawọn ti wọn gbarata lori bi CBEX ṣe fori ṣanpọn ṣakọlu si ọfiisi wọn to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, wọn si jẹ ọfiisi naa run, wọn ko ọpọlọpọ dukia bi tẹlifiṣan, ẹrọ amuletutu, aga ati awọn nnkan ọṣọ ile gbogbo t’ọwọ wọn ba lọ, bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ti lọọ pese aabo si adugbo naa lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search