Kwankwaso, Ọrọ Buruku Lo Ku To Fẹ Gbọ – Gomina Yusuf ti Kano

Gomina ipinlẹ Kano, Alhaji Abba Kabir Yusuf ti ọpọ mọ si Abba Gida Gida lo ti sọ oko ọrọ buruku pada si baba-isalẹ rẹ tẹlẹ ni idi oṣelu ṣugbọn ti aarin wọn ti daru iyẹn Rabiu Musa Kwankwaso.

Gomina Yusuf pe bi Kwankwaso ko ba ṣọra ṣe, oun ko ni kọ lati fi ọrọ buruku yẹyẹ rẹ. Gomina s’ọrọ yii lasiko ipolongo itagbangba kan to waye laipẹ yii ni ipinlẹ Kano nibi ti ọgọrọ awọn eniyan ti peju, to si dabi esi si awọn ọrọ kan ti Kwankwaso ti sọ nipa gomina naa l’asiko to n kopa ninu ifọrọwanilenuwo kan pẹlu ile-iṣẹ amohunmaworan kan to ṣe laipẹ yii.

Ninu ọrọ Gomina Yusuf, o lọ bayii pe “bawo ni ẹni ọdun mọkandinlaadọrin (69) yoo ṣe ma pe ẹni ọdun mẹtalelọgọta (63) ni ọmọ rẹ?” Gomina Yusuf sọ siwaju si pe “Ibọwọ f’agba ni mo fi n dakẹ tẹlẹ ṣugbọn ti ko gba ṣọ ẹnu rẹ, eti rẹ (Kwankwaso) yoo bẹrẹ si ni gbọ ọrọ buruku ti ko ni ba lara mu.”

Ẹ ranti pe ṣaaju ni Kwankwaso ti kọ s’ọrọ awọn ọrọ kan to fẹ ṣe bi ẹni yẹpẹrẹ Gomina Yusuf pe ọmọ ni Yusuf jẹ si Kwankwaso ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lakootan, Gomina Yusuf pe “mo gbagbọ ninu ki ipinlẹ Kano tuba tuṣẹ ṣugbọn ti n ko ni gba ki ẹnikẹni f’ẹnu ba mi jẹ, yoo di didan kin fọ’hun.”

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search