Ilumọ-ọn-ka arẹwa oṣere tiata to tun fẹran okoowo ṣiṣe nni, Mercy Aigbe ti ṣalaye pe ni gbogbo igba toun ba n ronu igbesi aye oun atẹyinwa, bo tilẹ jẹ pe oun fogo f’Ọlọrun fun aaye toun wa bayii, sibẹ o maa n dun oun gidigidi, oun si maa n kabaamọ lori igbeyawo pẹlu ọkọ aarọ ọjọ oun, iyẹn Ọgbẹni Lanre Gentry, eyi to fori ṣanpọn lọdun diẹ sẹyin, o ni iṣẹlẹ naa ṣi maa n gba omi loju oun.
Mercy Aigbe sọrọ yii nibi eto ifọrọwanilẹnu wo kan to ṣe pẹlu oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, Wasila Coded, lori ẹrọ ayelujara ti wọn pe akọle rẹ ni “Iriri Mi” laipẹ yii. Lẹyin ti obinrin to ṣe fiimu Ada Ọmọ Daddy yii ti sọrọ nipa adojukọ rẹ lori awọn fiimu to gbe jade, bo ṣe kuro yi pada lati ẹlẹsin kristẹni si ti ẹsin musulumi to si di Alaaja ọsangangan, ati bo ṣe n gbadun ọkọ rẹ keji yii, Alaaji Kazeem Adeoti tawọn eeyan tun n pe ni Adekaz, si, wọn bi i leere pe ki lohun to ba a lọkan jẹ julọ nigbesi aye rẹ.
Ibi yii ni Mercy, Iya ọlọmọ meji yii, ti tẹnu bọrọ, o ni: “Maa sọ pe igbeyawo mi akọkọ ṣi lohun to ba mi lọkan jẹ julọ laye mi, nitori teeyan ba ti ṣiyan lati ibẹrẹ, ko kii rọrun lati ṣe atunṣe si i mọ, amọ mo dupẹ temi ṣa.
Mi o gbadura igbe aye keeyan maa da tọmọ fun ẹnikẹni nitori ko rọrun rara o. Nigba ti mo wa ni sisi, mi o ronu ẹ ri pe irin-ajo aye mi le lọ bo ṣe lọ yii rara. Sibẹ, mo tun le sọ pe ọjọ ti inu mi dun ju ni ọjọ ti ọmọ mi obinrin kẹkọọ gboye jade ni fasiti ilu oyinbo. Inu mi dun jọjọ ni o, tori ko rọrun lati maa paarọ owo Naira si dọla nigba gbogbo, iṣẹ nla ni fun mi, amọ Ọlọrun duro ti mi titi mo fi ṣaṣeyọri.
Wọn tun beere lọwọ Mercy Aigbe pe amọran wo lo ni fawọn obinrin ti wọn n da tọmọ, iyẹn awọn single mother tabi baby mama lasiko yii, niṣe lo mi kanlẹ, o ni: Hmmn, akitiyan nla ni lati da nikan tọ ọmọ o, ṣe ti inawo abi ti imọlara abi ti iwa rere la fẹẹ sọ ni. Amọ maa gba wọn lamọran pe ki wọn ma ronu mọ lori inira ti wọn n la kọja.
Loootọ ko rọrun lati gbọkan kuro, amọ tẹẹ o ba ṣe bẹẹ, ẹ o nii le tẹsiwaju. Ọlọrun, ara yin ati awọn ọmọ yin ni kẹẹ sa gbaju mọ. Laipẹ laijinna, ẹ maa de ilẹ ileri.” Mercy Aigbe lo sọ bẹẹ.