Ile Mercy Aigbe to jona: Aṣiri nla foju hande
Oriṣiiriṣii ọrọ, ero, ifọrọwerọ ati isọrọsi lo ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii latari iṣẹlẹ ibanujẹ to ṣẹlẹ si gbajugbaja onitiata ilẹ wa to rẹwa bii egbin nni, Mercy Aigbe, ti ile olowo nla rẹ jona guruguru lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii. Bawọn eeyan ṣe n mefo, ti wọn n fi ookan kun eeji lati mọ ibi ti iṣẹlẹ aburu naa ti wa, awọn wo lo wa nidii rẹ, ṣe amuwa Ọlọrun ni abi ejo lọwọ ninu, bẹẹ ni wọn na’ka aleebu si awọn eeyan ti wọn gbagbọ pe awọn ni amookunṣika to wa nidii ijamba buruku yii.
Bẹẹ lọrọ naa ko yọ Mercy Aigbe funra rẹ silẹ, tori niṣe lawọn kan n da oun naa lẹbi, wọn loun lo fọwọ ara rẹ ṣe ara rẹ.
Ohun to tubọ mu kawọn eeyan fura lori iṣẹlẹ yii ni ti iṣọwọ-jona ile awoṣifila naa, lọjọ kẹta, ọsu Kejila, ọdun 2024 ti iṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Magodo, l’Ekoo, niṣe ni ina naa jo ajoran, lati yara si yara, o si buru debi pe ko ṣee ṣe lati mu abẹrẹ lasan jade nile ọhun laijona, gbogbo dukia olowo nla ni ina naa jo kanlẹ rau.
Lọjọ Wẹsidee, ọjọ keji ti iṣẹlẹ yii waye, orogun Mercy Aigbe, Abilekọ Funṣọ Adeoti, iyẹn iyawo akọkọfẹ Ọgbẹni Kazeem Adeoti ti i ṣe ọkọ wọn, kọ ọrọ kan sori ẹrọ ayelujara rẹ to mu kawọn ololufẹ rẹ bẹrẹ si i sọrọ kobakungbe si Mercy Aigbe, eyi si mu ki ara fu ọpọ eeyan si obinrin naa, o ṣetan, Yoruba bọ, wọn ni oriṣa jẹ ki n pe meji obinrin ko denu.
Ẹ o ranti pe Funṣọ Adeoti ni iyawo oloruka akọkọ lọọdẹ baale wọn, Kazeem, ọmọ mẹrin lo si ti bi fun ọkọ wọn, bo tilẹ jẹ pe orileede Amẹrika lọhun-un lo fi ṣe ibujokoo, ibẹ lo wa ki ọrọ ifẹ too ṣẹlẹ lọdun 2022 laaarin ọkọ rẹ ati Mercy Aigbe, iya ọlọmọ meji toun ati ọkọ aarọ ọjọ rẹ, Ọgbẹni Lanre Gentry, ti ja, ti wọn si ti pin gaari nigba yẹn. Bẹẹ ọrẹ ni Lanre Gentry ati Kazeem Adeoti fun igba pipẹ, bi Mercy si ṣe wọ ọọdẹ Kazeem yii ko dun mọ Iyaale rẹ, Funṣọ atawọn ọrẹ rẹ ninu, wọn ko si fi aidunnu wọn pamọ, bo tilẹ jẹ pe gele ‘ma-wo-bẹ’ ni Mercy de sọrọ naa, bẹẹ lọkọ rẹ tuntun huwa ipakọ ko gbọ ṣuti, ẹni ba woju iyawo ni yoo ri i pe o n sunkun, niṣe ni wọn n ba ere ifẹ tiwọn lọ ni rẹbutu.
Ọrọ ṣoki ti Funṣọ Adeoti kọ lede oyinbo sori ikanni Instagiraamu rẹ ni: “Grateful soul,” eyi to tumọ si “Ọkan mi moore o,” o si gbe fidio ara rẹ nibi to ti n gbadun aye ẹ l’Amẹrika si i. Lọgan lawọn ololufẹ rẹ ti ya bo ikanni ọhun, ti wọn si kọ ọkan-o-jọ’kan ọrọ sabẹ ọrọ iyaale Mercy Aigbe yii.
Obinrin kan, Judy Nwa sọ pe: “Ko le si alaafia fun awọn gbọkọ-gbọkọ o.”
Jully Julez ni: “Ile wọn ti jona o. Jẹ ki n kuku ba ẹ la ọrọ to n pẹ́ sọ lowelowe yii mọlẹ jare.” Sissy Zizzy kọ ọrọ tiẹ bayii: “Iwọ ni ẹni ti Ọlọrun ti n gbe ija rẹ ja, boya o mọ tabi oo mọ.”
Tina Akwa ni: “Ọlọrun lo n ṣẹgun fun ẹ o.”
Abagbodi sọ pe: “Arẹwa obinrin, Ọlọrun yoo maa ja fun ẹ niṣo.”
Eyi ti Cheesom kọ lo le ju, o ni: “Ok Mama, Ile awọn ọta wa jona deeru. Awa n gbọ ni o, a o dajọ o.
Ọlaiya naa sọ pe: “Maa yọ ni tiẹ, mama to rẹwa, Ọlọrun ti n ja fun wa niṣo.” Ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Tẹẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2023 to kọja ni Funṣọ Adeoti ṣedaro lori ikanni rẹ pe ọjọ naa lo yẹ ki oun ati ọkọ oun jọ ṣajọyọ ogún ọdun igbeyawo awọn, amọ oun gba f’Ọlọrun.
Yatọ si ti orogún Mercy Aigbe yii, awọn eeyan tun n na’ka abuku si oṣere-binrin onitiata to mu lẹnu bii abẹ nni, Lizzy Anjọrin. Wọn ni ko ki Mercy pẹlẹ, ko si ba a daro, wọn lo jọ pe inu rẹ dun si iṣẹlẹ buruku yii. Awọn to sọrọ ọhun lori ikanni Fesibuuku sọ pe latigba ti wọn ti fẹsun ole jija kan Lizzy ni Idumọta, l’Ekoo, ti ọrọ naa si di yankan-yankan nigba yẹn, Mercy ko da si i, ko gbeja Lizzy, ko si le gbeja rẹ loootọ, nitori ọrẹ ni Mercy ati Iyabọ Ojo, toun ati Lizzy jẹ ata ati oju ti ko fẹran ara wọn, bii ekute ati ologbo lawọn mejeeji ni gbogbo asiko yẹn.
Awọn mi-in tun fete kan ọkọ aarọ ọjọ Mẹrcy Aigbe, iyẹn Ọgbẹni Lanre Gentry. Bo tilẹ jẹ pe oun ati Mercy Aigbe ti kọ ara wọn silẹ, ti wọn si jawee fun ara wọn, ti ọkunrin naa si ti fẹ iyawo mi-in lẹyin naa ṣaaju ki Mercy too di ti Kazeem yii, sibẹ wọn ni inu Lanre ko dun pe ọrẹ timọtimọ oun, tawọn ti jọọ jẹ, tawọn si ti jọọ mu ni ko waa ri ẹni ti yoo fẹ, afi iyawo toun atiẹ jọ ja. O ṣetan, Yoruba lo n powe pe afẹni-laya kii fi oju ire wo’ni, wọn si tun ni ‘ya mi niyawo rẹ’ ko ṣee gbọ seti.
Amọ ṣa o, bawọn eeyan kan ṣe n ṣe aropọ ati ayọkuro lori ibi ti ijamba ina runle-runna yii ti wa, bẹẹ ni ọpọ awọn to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii n rọ Mercy Aigbe ati Kazeem Adeoti lati gba f’Ọlọrun, wọn ni gbogbo nnkan to pamọ lo han si Eledua, bẹẹ lawọn mi-in n ṣe ẹẹkẹ eebu lori ayelujara, wọn n ṣekilọ pe kawọn to n dana ọrọ yii silẹ yee ṣe gbeborun, ki wọn ma lọọ fi ori eku gbun tẹyẹ, ki wọn ma si sọ ohun ti oju wọn ko to.
Sibẹ naa, ina ọrọ yii ṣi n ja ranyin niṣo lori ẹrọ ayelujara di ba a ṣe n sọ yii.