Kollington O Ku O, Alaafia Ni Baba Wa - Awọn Alakoso Rẹ
Awọn alakoso agba onifuji nni, Alh. Kollington Kolawole Ayinla ti ko iroyin kan to n tan kaakiri danu pe olorin naa ti ku.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede eyi ti Shamsudeen Ilori buwọlu l’orukọ ẹbi ati awọn alakoso naa ni wọn ti pe iroyin ọhun ni irọ pọnbele to jina si ootọ.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, awọn kan ti wọn n wa ero lori ayelujara ni wọn bẹrẹ ahesọ ọrọ naa lati ko ipaya ba awọn ẹbi, ọrẹ ati ololufẹ olorin naa.
Wọn tẹsiwaju pe, koko bayi ni ara Kollington le to si wa ni alaafia ara, koda o n jaye ori rẹ pẹlu awọn mọlẹbi, ti o dẹ ṣi n fi orin fuji rẹ to kun fun ọgbọn da awọn eeyan lara ya.
Awọn alakoso naa ṣapejuwe iroyin ọhun gẹgẹ bii iṣẹ ọwọ awọn ika ẹda ti wọn n gbiyanju lati tabuku ilumọọka olorin naa.
Wọn wa kilọ fun awọn agbefọnranjade l’ori ayelujara lati ṣọra gidi nipa gbigbe iroyin ti kii ṣe ootọ, ki wọn maa ba ta’pa s’ofin bẹẹ, ni wọn rọ awọn eeyan lati maa wadi iroyin ti wọn ba ri ki wọn to gbaa gbọ.
Atẹjade naa tubọ wa fi ọkan awọn ọrẹ, ẹbi ati ololufẹ olorin naa balẹ pe alaafia ni Baba wa.
Kii ṣe igba akọkọ re ti olorin naa n jade wa ko iroyin iku rẹ danu lori ẹrọ ayelujara.
Abdulrasaq Kolawole Ilori ti gbogbo eeyan mọ si Alh. Kollington, jẹ ọkan lara awọn gbajugbaja ti wọn bẹrẹ orin fuji to si ko ipa ribiribi lati sọ orin fuji di eyi ti aye n gbọ.