ỌRỌ BURUKU: FAYOṢE ATI CUBANA GBE INA WOJU ARA WỌN

N ṣe ni ọrọ dabi ina ati ẹtu, ti nnkan si burẹkẹ l’aarin Isaac Fayoṣe to jẹ aburo gomina tẹlẹ ni’pinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ati gbajumọ olokoowo faaji (hospitality mogul), Pascal Okechukwu ti ọpọ mọ si C.P abi Cubana Chief Priest. Awọn ọrọ buruku kobakungbe ni wọn sọ si ara wọn l’ori ayelujara.

Ọrọ naa bẹrẹ pẹlu bi Fayoṣe ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn to wa lati inu ẹya Igbo pe iwa wọbia pọju fun wọn, nitori ti wọn kọ lati dasi ọrọ Mazi Nnamdi Kanu lati igba to ti wa ni ọgba itunirọ ni ipinlẹ Sokoto. O tọka si pe Sunday Igboho lo ti gba ominira rẹ, ti nnkan ko si mu Sheikh Gumi fun ṣiṣe egbe fun awọn jankoriko (bandit) ati agbesunmọmi (terrorist). Isaac wa f’ẹsun kan pe iru awọn gbajumọ lati inu ẹya Igbo bii C.P lo yẹ ki wọn o duroti Kanu ṣugbọn ti wọbia si mudunmudun oṣelu ko ni jẹ. Eyi gan-an lo fa ti C.P naa fi gba’na jẹ.

C.P ninu ọrọ ti ẹ sọ’ko ọrọ si Fayoṣe pe kinni ọdun mẹjọ ti oun ati ẹgbọn rẹ Gomina lo l’ori itẹ ja mọ fun ipinlẹ Ekiti ṣugbọn ti oun ni itọkasi awọn iranwọ ati apọnle ti oun ti mu ba ipinlẹ ati ẹkun oun.

Nigba ti ọrọ naa gbona de aarin kan, ni awọn mejeeji bẹrẹ si ni fi owo taka, ti awọn mejeeji dẹ fi iṣẹ bu ara wọn. Fayoṣe ni owo C.P ko mọ to si yẹ ko wa l’ẹwọn bo ba ṣe pe ilu dara ju bayii lọ. Cubana Chief Priest ni tiẹ pe ilara ati ipọnju lo n yọ Fayoṣe l’ẹnu.

Bi awuyewuye naa ti n lọ l’aarin awọn mejeeji yii ti wọn ti gbajumọ tẹlẹ naa l’ori gẹgẹ bi alagbaja ẹda, ni awọn eniyan n to l’ẹyin ọkọọkan awọn mejeeji, ti awọn miran si gbagbọ pe ṣago to n bu’go l’ọrọ awọn mejeeji.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search