Nasboi: Ma a Kọ Iyawo Mi Si’lẹ L’ọjọ To Ba Ro Ẹjọ Wa Lori Ayelujara

Irawọ alawada, olorin ati amuludun ti ọpọ mọ si Nasboi lo ti fi ero rẹ han pe bi oun ba gbe iyawo, ti obinrin ba gbe ẹjọ aarin ara awọn mejeeji to le e yanju ninu ile de ori ayelujara, n ṣe ni oun yoo kọ iru aya bẹẹ si’lẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo ikanni X rẹ lo ti sọ ero rẹ di mimọ.

Nasboi, ẹni to tun fi le’de ṣaaju laipẹ yii pe oun ri ẹbun owo gba lat’ọwọ gbajugbaja olorin, Burna Boy lo tun gbe omiran ja’de nipa iwoye lori oun ti obinrin le ṣe to le tu wọn ka.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search