Minisita fun oun Amuṣagbara lorilẹede Naijira ti Aarẹ ṣẹṣẹ yan Joseph Tegbe ti kọ awọn ọrọ to n lọ l’agbọn kan pe oun ṣe ileri lati wa atunṣe si ọrọ opo to gbe ina ẹlẹtriki duro lorilẹede Naijira.
Nigba to n sọrọ latenu Agbẹnusọ rẹ, Adeọla Adelabu ṣapejuwe ọrọ naa bi aṣigbọ ọrọ t’oun sọ nibi ifọrọwerọ nile Aṣofin Agba ilẹ wa l’ọjọ kẹfa oṣu yii.
Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ, Adelabu ni nkan ti Tegbe sọ ni pe awọn n ṣe ipade pẹlu awọn ti ọrọ kan lori akoko ti atunṣe inu ẹka ohun amuṣagbara yoo gba bẹẹ ni awọn n ṣagbeyewo awọn ohun to n fa ailọdeedee ninu ẹka naa.
Minisita fun ohun Amuṣagbara lorilẹede Naijira ti Aarẹ ṣẹṣẹ yan Joseph Tegbe
Gẹgẹ bi ọrọ naa ṣe fi han Tegbe fi ọkan awọn ọmọ ile Aṣofin Agba lọkan balẹ pe ni ọgọrun ọjọ akọkọ ni oun yoo ti maa gbe awọn igbesẹ ti yoo mu atunṣe ba ẹka naa ṣugbọn atunṣe ti awọn eeyan a fi oju ri yoo han gbangba lẹyin ọdun kan.
Adelabu tẹsiwaju pe awọn atunṣe naa yoo da le imugbooro ẹka naa, atunṣe ẹka afẹfẹ gaasi ati idagbasoke gbogbo ẹka naa lapapọ kaakiri orilẹede Naijiria.
Lori ọrọ owo ina, Tegbe f’ọkan awọn ọmọ ile Aṣofin Agba balẹ pe oun a ri pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria o jẹ yiyan jẹ.
Adelabu wa fi da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju pe Tegbe ṣetan lati ba awọn akọroyin ṣe daadaa ati lati ṣe afihan gbogbo igbesẹ atunṣe fun gbogbo eeyan ri.
Ti ẹ o ba gbagbe, Aarẹ Tinubu yan Tegbe laipẹ yii lẹyin ti Minisita tẹlẹ fun ohun Amuṣagbara, Adebayọ Adelabu kọwe fiposilẹ lati dije dupo Gomina nipinlẹ Ọyọ.