Gbajumọ amuludun, Pascal Okechukwu “Cubana Chief Priest” to tun jẹ alakoso fun ẹgbẹ “City Boy Movement” ẹka ti ipinlẹ Imo lo ti fi idi rẹ’mi ninu eto idibo abẹnu ninu ẹgbẹ oṣelu APC l’eyi to kopa ninu rẹ lati le ja fun jijẹ ọmọ-oye ẹgbẹ oṣelu naa ti yoo ṣ’oju ẹkun idibo Orsu/Orlu/Iwọ-oorun Oru ni ile aṣoju-ṣofin orilẹ-ede Naijiria ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Chief Priest ẹni ti ko bikita nipa awuyewuye to pọ ni ori rẹ lati igba to ti kede ipinu rẹ lati darapọ mọ ipolongo oṣelu fun saa keji Aarẹ Bọla Tinubu ni ọfisi latari ẹgbẹ “City Boy Movement,” to si tun pada jade pe fun idibo abẹnu ni ẹkun idibo rẹ.
Botilẹjẹ pe, esi idibo abẹnu naa l’ẹkunrẹrẹ ko ti han’de tan ṣugbọn ti ọpọ awọn onwoye l’ori ayelujara ti bẹrẹ si ni fi ero wọn si’ta lori ifidi rẹmi Chief Priest.
Bi ọpọ ti n da yegede rẹ pe ko rọwọ mu ati pe oṣelu kii ṣe ẹka amuludun ati afẹ ti oun ti wa, bẹẹ ni awọn kan n ki ku ọmọ akin ṣe nitori oṣelu ko rọrun rara to si lẹtọ lati yin Cubana Chief Priest l’awo.