Ẹni to ti figba kan wa nile Big Brother Naija Queen Mercy Atang leyi to ja gbangba pẹlu aṣọ to wọ lọsi ibi ami-ẹyẹ AMVCA tọdun yii lo ti jade wa ṣalaye oun ti oju rẹ ri lẹyin aṣọ aramanda rẹ.
Queen ṣalaye bi aṣọ ọhun ti wọn fi ẹẹdẹgbẹta burẹdi ṣe fa ẹyin didun gidi fun oun lẹyin ami-ẹyẹ naa. Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan lo ti ṣalaye pe gbajugbaja aranṣọ Tiannah Empire lo gbe ọgbọn aṣọ naa kalẹ.
O tẹsiwaju lati ṣalaye bi aṣọ naa ṣe wuwo gidi leyi to fa ki ibadi oun fẹ kan debi pe oun pada ni egbo l’ẹyin.
O ṣalaye pe ọpọlọpọ ọsẹ l’awọn lo lori aṣọ naa ko le jade daadaa. O fi kun pe oun sunkun nigba ti wọn n wọ aṣọ naa si oun l’ọrun nitori bo ṣe wuwo to.
Queen ni idi ti oun fi wọ aṣọ naa ni pe oun fẹ ṣafihan okowo oun leyi to jẹ pe amunidara oun lo mu aba naa wa. O tẹsiwaju pe amunidara oun yii lo fun oun nigboya lati jade lọ sibi ami-ẹyẹ naa bi o tilẹ jẹ pe oun o mọ pe aṣọ naa le mu aduru awuyewuye to mu dani naa.
Queen Mercy Atang ni o di ilumọọka latari aṣọ to wọ lọ sibi ami-ẹyẹ AMVCA ti wọn fi burẹdi ṣe to si fi ẹwa agọnyin ṣe baagi to gbe lọwọ.