Gbajugbaja ajafẹtọ, Aisha Yesufu lo ti sọ pe igba ti ẹ yo yatọ bi oun ba le wọle gẹgẹ bii Aṣofin-Agba to n ṣ’oju olu-ilu orilẹ-ede Naijiria, iyẹn ilu Abuja ni ile-aṣofin apapọ.
Yesufu to jẹ ọkan pataki ninu awọn alatẹle Ọgbẹni Peter Obi ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023 ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, to si tun tẹle bọ si inu ẹgbẹ oṣelu NDC lati ẹgbẹ ADC lo sọrọ lori amohunmaworan nipa erongba rẹ ati ti Peter Obi ninu oṣelu ọdun 2027.
Ninu ọrọ rẹ, Yesufu to n gbero lati dije du ipo aṣofin-agba lati inu ẹgbẹ oṣelu NDC jẹ ko di mimọ pe oun ko fi iṣẹ ajafẹtọ silẹ ṣugbọn ti oun gbero lati mu oṣelu mọ ki oun tun le ran ilu lọwọ si. A ti pe oun fẹ mu iyatọ ba jijẹ aṣofin kuro ni wiwọ aṣọ olowo nla ati ọkọ bọginni di eyi ti wọn yoo fi ma jisẹ ilu.
O wi bayii pe “Mo gbero lati lọ ba awọn ara ilu ni gbogbo agbegbe lati beere ohun ti wọn nilọ, pẹlu akọsilẹ ati adehun eyi ti wọn le gbamu lati bi mi ni ọjọ iwaju, yatọ fun ọrọ didun ti wọn ti ma n gbọ tẹlẹ.”
Nipa bi oun ati Peter Obi ṣe ti paarọ ẹgbẹ lati LP wọ ADC wọ inu ẹgbẹ NDC ti wọn wa lọwọlọwọ, o jẹ ko di mimọ pe, ọgbọn ni awọn n da nitori awọn ti ri oye ọjọ iwaju lori awọn idojukọ awọn ẹgbẹ oṣelu ti awọn ti kuro, to si jẹ apẹrẹ ọgbọn-inu to yatọ fun aleebu oṣelu.
Lakootan, Yesufu ni oun ko bẹru lati dije koju awọn oloṣelu kanjan to ṣeeṣe ki awọn ẹgbẹ to ku o fa silẹ dipo bẹẹ ti oun gbaradi lati kopa ninu ibo abẹnu lati jẹyọ gẹgẹ bii ọmọ oye ẹgbẹ oṣelu naa lati le kopa ninu idibo ile-aṣofin apapọ lọdun 2027.