Ikọ PSG Gba’ṣọ L’ara Arsenal L’ọjọ Ẹyẹ Idije UEFA

N ṣe ni ariwo ta gee lẹyin bii wakati meji ti nnkan ti pa lọlọ, latari ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba alagbara to waye laarin ikọ PSG ati Arsenal ninu idije ife-ẹyẹ UEFA eleyii to mi igboro titi ni nnkan irọlẹ oni.

Ikọ Arsenal lo kọkọ r’ọwọ mu ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti Kai Havertz mi awọn ni aarin iṣẹju mẹfa akọkọ ayo naa ki Ousmane Denbele ti inu ikọ PSG to mi awọn ni iṣẹju kẹrinlelọga lati sọ ayo naa di ọmi alayo kọọkan.

Lẹyin ọpọ jija raburabu l’aarin ikọ mejeeji lati fi agba han, ayo naa pada wa s’opin nipasẹ goli-wo-mi-n-gba-si-ọ (penalty shootout) to pari pẹlu ami ayo mẹta si mẹrin l’eyi ti ikọ Arsenal fi fidi rẹ’mi latari bi agbabọọlu wọn, Gabriel se padanu goli-wo-mi-n-gba-si-ọ ti ẹ.

Ẹwẹ, ọtọtọ bayii ni esi ayo naa lo jasi lọdọ oriṣiriṣi awọn ololufẹ aree bọọlu. Awọn kan to jẹ ololufẹ ikọ Arsenal n karibọnu gidi pe ikọ Arsenal naa sọ anfani nla naa nu, bẹẹni awọn miiran gbagbọ pe PSG gan-an ni ade naa tọ si ninu awọn orilẹ-ede to wa nilẹ.

Ẹ ranti pe ikọ Arsenal lo ṣẹṣẹ gbe igba oroke ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi iyẹn Premier League, ti wọn si tun gbero ati fi ọba ife-ẹyẹ UEFA de l’ade ṣugbọn ti igbiyanju naa pakaṣọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search