Awọn Agbesunmọmi O Le Maa Dun Mọhuru Mọhuru Mọ Wa Lorilẹede Naijiria, A Ju Bẹẹ Lọ – Olurẹmi Tinubu

Aya Aarẹ Orilẹede Naijiria, Olurẹmi Tinubu ti sọ pe opin maa de ba ipenija eto aabo to mẹhe lorilẹde Naijiria nipa igbiyanju ijọba apapọ, atilẹyin awọn ẹṣọ alaabo ati ifọwọsowọpọ awọn ajọ agbaye.

O sọ eyi di mimọ nigba to ṣe abẹwo ẹnlẹ nbẹun si ipinlẹ Ekiti nibi to ti ṣe ipade pẹlu ajọ awọn lọba lọba ni Ado Ekiti.

Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ rẹ Busola Kukoyi fi lede Olurẹmi ni orilẹ-ede Naijiria ti tobi ju ki awọn kan maa dun mọhuru mọhuru mọn lọ.

O tẹsiwaju pe Aarẹ Tinubu n ṣiṣẹ takuntakun lati f’opin si eto aabo to mẹhe to si n ṣapejuwe bi nkan ṣe ri gẹgẹ bi ohun to n fa idaamu ọkan bẹẹ lo n fi ireti gbe pe iyatọ maa wa pẹlu awọn igbesẹ to n lọ lọwọ.

Olurẹmi ni fun apẹrẹ, orilẹede Amẹrika n ṣe iranwọ ati pe ọpọ awọn ti wọn n da omi alaafia orilẹede yii ru o ki n ṣe ọmọ orilẹede Naijiria.

O ni biotilẹ jẹpe oun o le sọrọ pupọ lori ẹ nitori ọrọ ikọkọ ṣugbọn yatọ si orilẹede Amẹrika, orilẹede France ati awọn orilẹ-ede agbaye loriṣiriṣi ni wọn ṣetan lati ran orilẹede Naijiria lati koju awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ti wọn n da omi alaafia wa ru.

Aya aarẹ wa fi awọn araalu lọkan balẹ pe eto aabo to mẹhe ko ni pẹ d’oun igbagbe bẹẹ lo rọ awọn eeyan paapaa julọ awọn obinrin lati tẹpa mọ adura nitori Ọlọrun n bẹ lori itẹ.

Asiko yii ni ipe n lẹ si f’awọn ijọba lati gbe igbesẹ akin lori eto aabo.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search