Eto Isinku Alex Ekubo Di Oju-ọja F’awọn Ole Agbefoonu

Tẹle ipapoda gbajugbaja arẹwa oṣerekunrin Alex Ekubo, ẹni to dagbere f’aye lẹni ogoji (40) ọdun l’at’ari aisan jẹjẹrẹ, isin aṣalẹ orin onigbagbọ waye fun Ekubo ni ilu Eko ni’bi ti ẹbi, ara, ojulumọ ati ọkan-o-jọ-kan awọn ilumọọka amuludun ti pejọ lati bu ọla fun gbajumọ oṣere naa to ti di oloogbe.

Ọgọrọ awọn eniyan to wa ni’bi eto naa lati bu ọla fun Oloogbe Ekubo lo kosi aṣọ funfun balau yatọ fun awọn perete to wa awọ miiran. Diẹ ninu ọgọrọ awọn ilumọọka to wa ni – Ayọ Makun; Cubana Chief Priest; Stan Nze; Tach; Nosa Rex; Daddy Freeze; Bambam; IK Ogbonna; Nkechi Blessing; Ẹja Nla Faniran ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Si iyalẹnu ọpọ eniyan, l’asiko ti eto orin isin onigbagbọ n l’ọwọ fun Ekubo ni ẹrọ ibanisọrọ awọn kọọkan ni’bi eto naa di awati. Eyi ṣeeṣe ko jẹ iṣẹ awọn alailẹriọkan alafọwọra, ole aji-foonu.

Oniruuru awọn eniyan lo ti wa n s’ọrọ nipa bi ọpọ ẹrọ ibanisọrọ to le ni marun-un ṣe di awati ni’bi eto ibanikẹdun oku. Awọn kan juwe rẹ gẹgẹ bii iwa ọdaju ati aini-itara ọmọniyan.

Gbajugbaja arẹwa oṣerebinrin ti ọpọ awọn eniyan mọ si Bambam lo kọkọ fi igbe ta l’ori ayelujara pe foonu oun ti di awati ni’bi eto orin iyin Ekubo.

Stan Nze, gbajumọ oṣere Nollywood naa ko gbẹyin, ninu fọnran ti ọkunrin ti kii ṣaba s’ọrọ l’ori ayelujara naa ṣe lo ti ni ọkan oun gb’ọgbẹ l’atari iṣẹlẹ naa nítorí o ti wa han daju pe ijọba abi awọn adari nikan kọ ni iṣoro wa l’orilẹ-ede Naijiria nitori ọpọ awọn ara-ilu gan-an lo jẹ ika ẹda alaini-ibẹru-Oluwa ati alailaanu ọmọniyan.

Ko tan si’bẹ, oniruuru awọn eniyan l’ori ayelujara lo tin gb’ara ta l’ori iṣẹlẹ pe ko bojumu bẹẹ ni awọn miran n beere pe bawo lo ṣe le jẹ pe ẹrọ ibanisọrọ bii mẹwa di awati mọ awọn agbalagba l’ara pe ọrọ naa ru’ju diẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search