Adichie Wọ Ile-iwosan Lori Iku Ọmọ Rẹ

Gbajugbaja onkọwe ‘binrin Chimamanda Ngozi Adichie ti f’ẹsun kan ile-iwosan Euracare Multi-Specialist Hospital fun ailamojuto gidi nidi ilera ati igbiyanju lati bo awọn nkan to sẹ’ku pa ọmọ rẹ pẹlu bi wọn ṣe gbe ipẹjọ oun si gbangba.

Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ, Adichie ṣalaye awọn iṣẹlẹ to fa iku ọmọ naa.

O ni ọmọ naa ṣeṣe l’ọpọlọ latari abere oloorun kan ti dokita to ni ṣe pẹlu ifunilabẹrẹ oorun, Dr. Titus Ogundare leyi to pada ṣokunfa iku ọmọ naa.

O ni yatọ si ọfọ to ṣe latari aimojuto wọn, ile-iwosan naa tun wu awọn iwa aiṣootọ bii, kikọ iwe-ẹri iku ti ko ṣe deede nitori wọn kọ pe aarun yirun yirun (Meningitis) lo ṣe’ku pa.

O ni wọn tun kọ lati pese iwe to niṣe pẹlu ilera ọmọ naa ni pipe fun ẹbi oun bẹẹ ni wọn tun lo gbolohun ti ko fi itara ọmọ han ninu iwe ipẹjọ ti wọn si pe ohun to ṣẹlẹ ni aawọ.

O tẹsiwaju pe niṣe ni wọn mọọmọ n da ipẹjọ duro pẹlu bi o ṣe jẹ pe awọn ni wọn bẹrẹ ẹjọ naa.

Adichie ṣalaye bi ọrọ naa ṣe ti fa iporuru ọkan fun oun ti oun o si tii ni anfaani lati kẹdun ọmọ oun to ku.

O sọrọ lori ọkan lara awọn oga agba ile-iwosan naa to gbiyanju lati yi lọkan pada lori ẹjọ naa ki orukọ rẹ ma baa yi ẹrẹ.

O ni ipẹjọ naa wa lati ṣe iwadi ohun to sẹ’ku pa ọmọ naa kii ṣe ijẹjọ tabi ọna ati gba owo gba-ma-binu.

Adichie ni oun mọọmọ fi lẹta naa sita lati jẹ ki gbogbo eeyan mọ ohun ti ile-iwosan naa n danwo nitori didakẹ tumọ si pe wọn oun n gba wọn laaye.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ keje oṣu kini ọdun yii ni ọkan lara awọn ibeji Adichie, Nkanu Nnamdi Adichie-Esege gbẹmi mi ni oṣu kọkanlelogun ni ile-iwosan Euracare. Lẹyin eyi ni Adichie jade wa sọrọ pe aimojuto lo ṣe’ku pa ọmọ oun.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search