Gomina Abiodun Ni Ipinlẹ Ogun Wa Digbi Lati Koju Igbesunmọmi

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọ-ọba Dapo Abiodun ti kede pe iṣejọba oun ti wa l’akọ lati doju ija kọ eto aabo to mẹhe kaakiri orilẹede Naijiria bẹẹ lo n ṣaṣọloju awọn akanṣe eto onimọ ẹrọ igbalode lati ṣe alekun eto aabo ẹmi ati dukiya.

Gomina sọ eyi nibi ipade ọgbọn inu ti ẹgbẹ oṣelu APC to waye l’agbegbe Ibara nilu Abeokuta. O fi ọkan awọn araalu balẹ pe bi o tilẹ jẹ pe eto aabo o le dọindọin kaakiri orilẹede Naijiria lọwọ yii iṣejọba oun maa gbe igbesẹ to tọ lati ri pe awọn ọdaran o raye nipinlẹ Ogun.

O tẹnpẹlẹ mọ pe iṣejọba oun a ri pe aabo wa f’awọn araalu pẹlu awọn ilana ọlọgbọn inu ati ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo ati awọn araalu.

O tẹsiwaju pe awọn daju le ṣiṣọ awọn ile-iwe gbogbo pẹlu alekun iṣọ kaakiri awọn ile-iwe t’oun ti fifi awọn ẹṣọ alaabo si awọn agbegbe to yi wọn ka nitori pe ọjọ-ọla ipinlẹ naa ni awọn ogo wẹẹrẹ jẹ, o si ṣe pataki lati daabobo wọn.

Gomina Abiodun wa fi ifọkanjin rẹ han lati ṣe imugbooro igbe-aye rere f’awọn araalu ati lati rii pe wọn jẹ anfaani ijọba awaarawa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search