Oṣere tiata tẹlẹ to ti ya si’di oṣelu bayii, Desmond Elliot lo ti ni oun ri ara oun gẹgẹ bii ọtọlorin oloṣelu ti tiẹ yatọ, iru oloṣelu ti kii k’owo jẹ abi gbe owo ilu mi bi kalokalo. O ni gbogbo asiko ti oun ti lo ni ipo ijọba l’oun ti fi sin ilu, t’oun si mu idẹrun ba awọn eniyan.
Elliot sọ eyi mọ’rọ l’ori eto “The Morayo Show” to ti jẹ alejo laipẹ yii, ni’bẹ lo ti s’ọrọ ni’pa idari, iṣejọba ati awọn ohun to rọ mọ wiwa ni’po ijọba, bẹẹ lo t’ẹnumọ pataki iwa irẹlẹ l’aarin awọn oloṣelu.
Oloṣelu naa to tun jẹ aṣofin to n soju ẹkun idibo Surulele kinni ni ile aṣofin ipinlẹ Eko pe “Iru oloṣelu t’emi kii ji’wo, emi kii ja’le. Ti ẹ ba wo Surulele bi ọdun mẹwaa sẹyin, ibi to buru jọjọ ni lati gbe… Ṣugbọn l’oni ina-ọba, eto ilera ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ti wa.”
Siwaju si, Elliot rọ awọn oloṣelu lati ma jẹ ki agbara ipo o ko si wọn l’ori nitori ipo ilu fun igba diẹ ni.
O pe “gbogbo wa la ma ku l’ọjọ kan. A o le wa titi.
O fikun pe awujọ n fi ọkan si bibeere lọwọ awọn eeyan nipa awọn iṣẹ ọwọ ti wọn ni, ti wọn si n f’oju pa awọn ti wọn ni ẹbun l’awọn ẹka to ṣe pataki rẹ.
Seun ni titi di igba ti ijọba ba pese awọn akanṣe eto fun gbogbo awọn to l’ẹbun, o maa nira fun ọpọ awọn ọdọ lati ri anfaani ti yoo ran agbara wọn lọwọ.