Igbẹyin Oṣere Yi Mr. Ibu Yii Ma Ga O

Igbẹyin Oṣere Yi Mr. Ibu Yii Ma Ga O

Awọn mọlebi gbajugbaja oṣere ati apanilẹrin to di oloogbe, John Ikechukwu Okafor ti gbogbo eeyan mọ si Mr. Ibu ni wọn ti jade wa sọ nkan ti oju wọn ti ri lẹyin iku rẹ.

Nigba ti wọn n sọrọ nigba ti agbefọnranjade l’ori ayelujara kan, King Mitchy lọ ṣe abẹwo si wọn, awọn ẹbi naa ṣalaye pe ọmọ obinrin kan ṣoṣo to bi ati awọn ọmọ ọkunrin rẹ mejeeji ni wọn o si ni ile-iwe mọ nitori ko si agbara.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni awọn ti n gbe lai ni omi ati ina fun ọpọlọpọ ọsẹ bayi nitori awọn o ri owo san.

Iya awọn ọmọ naa lo ṣalaye pe nkan le gidi fun awọn bayi. O ni oun o ri owo ile san nitori naa omi kọnga l’oun n pọn koda lati bii oṣu meji ni wọn ti ge ina awọn ti nkan o dẹ rọrun rara.

Nigba ti ọmọ rẹ obinrin n sọrọ, o gboriyin fun iya rẹ fun gbogbo akitiyan rẹ lati pese fun awọn bẹẹ lo n rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria paapaa julọ awọn ti wọn wa l’agbo amuludun lati ran awọn l’ọwọ.

O fikun pe awujọ n fi ọkan si bibeere lọwọ awọn eeyan nipa awọn iṣẹ ọwọ ti wọn ni, ti wọn si n f’oju pa awọn ti wọn ni ẹbun l’awọn ẹka to ṣe pataki rẹ.

Seun ni titi di igba ti ijọba ba pese awọn akanṣe eto fun gbogbo awọn to l’ẹbun, o maa nira fun ọpọ awọn ọdọ lati ri anfaani ti yoo ran agbara wọn lọwọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search