Ibinu Lo Jẹ Ki N Fi Ẹgbẹ Oṣelu APC Silẹ – Iyabo Obasanjo

Ibinu Lo Jẹ Ki N Fi Ẹgbẹ Oṣelu APC Silẹ - Iyabo Obasanjo

Ọmọ Aarẹ tẹlẹ ri l’orilẹ-ede Naijiria, Olusegun Obasanjo, Iyabo Obasanjo ti ṣalaye idi to ṣe kọ’we fi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) silẹ.

Nigba to n sọrọ nibi eto kan ti wọn pe si, Iyabo ṣalaye pe oun fi ẹgbẹ naa silẹ nitori ibinu pe ẹni ti ẹgbẹ fa kalẹ nipinlẹ Ogun kọ lati mu ileri to sẹ f’oun ati awọn ọmọ ẹyin oun ṣe.

 

Ni ọjọ ọjọru ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ogun  ki Iyabo kaabọ sinu ẹgbẹ naa lẹyin to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Oṣu kinni ọdun yii ni Iyabo to ti f’igba kan jẹ sẹnetọ, pada sidi oṣelu lẹyin ọdun mẹẹdogun. O darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC nibi to ti kede erongba rẹ lati dije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun.

Ojo kọkanlelọgbọn oṣu karun-un ọdun yii ni Iyabo fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lẹyin ti o padanu tikẹti lati dije dupo gomina. O ni aisi apọnle, iwa ọdalẹ ati didari apa kan da ikan si lati ọdọ awọn olori ẹgbẹ lo fa t’oun fi f’ẹgbẹ naa silẹ.

Iyabo Obasanjo lo ti fi igba kan jẹ kọmiṣọna fun eto ilera nipinlẹ Ogun lati ọdun 2003 si ọdun 2007. Odun 2007 lo wọle idibo gẹgẹ bii sẹnetọ to ṣ’oju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun.

Ọdun 2011 lo fi oṣelu silẹ nigba to padanu idibo iwọle ẹlẹẹkeji rẹ si ile-igbimo aṣofin agba.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search