Ọkọ Mi Kii Binu Bi Ọkunrin Miiran Ba Jẹ Ete Mi Ninu Ere – Toyin Abraham

Ọkọ Mi Kii Binu Bi Ọkunrin Miiran Ba Jẹ Ete Mi Ninu Ere - Toyin Abraham

Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham lo ti ja’de wa sọ pe ọkọ-ile rẹ, iyẹn Kọla Ajeyẹmi t’oun naa jẹ oṣere tiata bii ti ẹ ni kii binu rara bi oun ba f’ẹnu ko ọkunrin miiran l’ẹnu ninu ere agbelewo nitori igbagọ kikun to wa l’aarin oun ati ọkọ oun.

Toyin lo sọ eyi l’ori eto “The Morayo Show” ni’gba to n dahun si ibeere atọkun pe boya ọkọ rẹ a ma a j’owu pe aya oun jẹ oṣere tiata, ati pe boya aala wa l’ori ohun ti ọkọ rẹ le gba mọ’ra. Atọkun wa bi ni pato ni’pa iṣẹlẹ kan ti Toyin ati gbajugbaja oṣerekunrin, Gabriel Afọlayan ti n f’ẹnu ko’nu.

 

Idahun Toyin ni pe, kosi ohun to jọ ibinu abi owu jijẹ pẹlu ọkọ oun ati pe Gabriel Afọlayan yẹn eeyan oun daadaa ni, iṣẹ ere l’asan si ni if’ẹnukonu naa jẹ.

Toyin pe “Mo le fi ẹnu ko ẹnikẹni l’ẹnu. Awo mi ni Gabriel.”

Ko tan si’bẹ, Toyin tun ni awọn to jẹ aya f’awọn oṣere akẹgbẹ oun l’ọkunrin gan-an kii gba iru ohun bẹ s’odi nitori to ye wọn daadaa pe iṣẹ ere l’asan.

O wa tẹsiwaju pe, gbogbo nnkan ni oun le ṣe ṣugbọn bi ti agbere kọ nitori ko si ninu iwa oun rara.

Ẹwẹ, l’ori eto naa bakanna ni Toyin ti ṣe alaye idi ọpọ awọn sinima nla nla paapaa julọ ti sinima fi ma n ja’de ni December iyẹn oṣu kejila ọdun, o ni nitori pe asiko ọdun ti gbogbo nnkan ma n sọkutuwọwọ ṣugbọn ti awọn sinima kọọkan ti o ja’de l’asiko miiran naa ti fi han pe dandan kọ ni kii iṣẹ sinima jẹ opin ọdun ko to le ta.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search