Idunnu Ṣubu L’ayọ Fun Taye Currency Bi Ọmọ Rẹ Ṣe Di Agbẹjọro

Idunnu Ṣubu L'ayọ Fun Taye Currency Bi Ọmọ Rẹ Ṣe Di Agbẹjọro

Gbajugbaja onkọrin Fuji,  Taye Adebisi ti ọpọ eeyan mọ si, Taye Currency lo ti ṣajọyọ pe ọmọ rẹ, Samsudeen Adebisi di agbẹjọro.

Onkọrin naa to jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan lo dawọ idunnu lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ. O ṣapejuwe oriire ọhun gẹgẹ bii ere iṣẹ takuntakun lati ọdun to pẹ, ifọkanjin ati suuru gidi.

Nigba to fi fọnran kan lati ibi ayẹyẹ naa lede, o fi idunnu rẹ han pe ọmọ naa wu oun lori. O wa gba l’adura pe, yoo ṣe aṣeyọri n’idi iṣẹ naa.

Fọnran ọhun lo ṣe afihan ọmọ naa ninu aṣọ iyi awọn agbẹjọro pẹlu Baba rẹ ti wọn jọ n di mọ ara wọn pẹlu idunnu ati ayọ.

Aṣeyọri yii lo jẹ alekun fun Taye Currency lori awọn ọmọ rẹ to maa n ṣapejuwe wọn gẹgẹ bii iwuri to julọ fun, bẹẹ lo maa n fi idunnu rẹ han ni gbogbo igba pe awọn ọmọ naa n ṣe daadaa ni gbogbo ẹka ti wọn wa.

Taye Currency lo jẹ ọkan lara awọn ti wọn n lewaju l’agbo Fuji pẹlu bo ṣe bẹrẹ iṣẹ orin ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

Ọpọ awọn ololufẹ ati alabaṣiṣẹpọ ni wọn ti ki onkọrin naa ati ọmọ rẹ ku oriire fun iroyin ayọ naa.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search