Funkẹ Akindele: Iya Jẹ Kisa Si Mi L’ara Nigba Ti Mo Wa Ni Unilag

Funkẹ Akindele: Iya Jẹ Kisa Si Mi L'ara Nigba Ti Mo Wa Ni Unilag

Gbajumọ oṣere to tun jẹ agbesinima jade, Funkẹ Akindele lo ti tu aṣiri ina nla ti wura rẹ la kọja ko to di ohun ti gbogbo aye n fẹ. Gbogbo ipọnju ti oju rẹ kan nigba to jẹ akẹẹkọ ni fasiti Unilag nipinlẹ Eko l’aarin awọn ohun miiran ni oṣere yii mẹnuba lọtẹ yii. Koda, ko ṣai ṣalaye idi to fi ma fi ijo jijo ta sinima rẹ to ba gbe ja’de.

Funkẹ lo tan imọlẹ si ọpọ awọn ohun ti aye ko mọ nipa rẹ l’ori eto kan pẹlu ile-iṣẹ BellaNaija to ti kopa laipẹ yii.

Ninu ọrọ Funkẹ, o ni ko si iṣẹ ti oun o ṣe tan l’asiko to n kawe ninu ọgba Unilag l’Eko. O ni ṣe iṣẹ awọn abaniṣeekanna l’oun fẹ sọ ni iyẹn (nail technician) ti oun kan f’oju si lati ọọkan l’agbagbe Yaba ki oun to ma fi awọn eniyan koṣẹ l’adugbo abi ti iṣẹ awọn aṣojuloge (iyẹn makeup artiste) l’oun fẹ sọ. Koda nigba miiran oun a tun ma ṣe keeki ta f’awọn eeyan. O ni gbogbo iṣẹ l’oun f’oju si ni’kọọkan nitori ati le gbọ bukata ile-ẹkọ.

O ṣ’aleye pe irinajo naa ko rọrun rara sugbọn ti ohun ti ti kekere ni akitiyan ti oun si j’ara mọ’ṣẹ. O ni ọjọ ti ẹ n bẹ ti oun ṣe eekanna fun ẹnikan, n ṣe ni onitọhun bu ifọti gbona jo oun nitori radarada to n ṣe s’ọwọ onibara naa. Amọ ṣa oun ko jẹ ki eyi da omi tutu si oun l’ọkan rara.

Ko tan si’bẹ, Funkẹ tun ni Bimpe Ọnakọya gbajumọ aṣojuloge jẹ onibara oun nigba naa to ma n ra keeki l’ọwọ oun, to fi wa di pe obirin n ṣe oju Funkẹ l’oge, t’oun naa si n fi oju si oriṣiriṣi, koda oun f’oju si iṣẹ irun didi.

Eeyan yoo ṣe bi ko ju bẹẹ lọ, Funkẹ tun ni oun tun fi igba kan ṣe iṣẹ abaniwa’ṣọ loko ere iyẹn (costumier) ati abaniwale fun ere iyẹn (location manager). Funkẹ ninu awọn ti oun ti wa aṣọ fun gẹgẹ bii oṣere nigba ni Bukky Wright ati Iyabọ Ojo t’oun ti ẹ mọ pe ogo oun maa pada de.

Ogbontarigi oṣere tun ṣalaye pe bi oun ba gba iṣẹ abaniwale fun ere agbelewo, bi wọn ba san bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun (100k) oun yoo fun onile ni ẹgbẹrun l’ọna aadọrin (70k) ti oun yoo si di ẹgbẹrun l’ọna ọgbọn iyen (30k) to ba ṣẹku mu.

O ni gbogbo awọn nnkan wọn yii lo ran oun l’ọwọ l’onii lati jẹ akinkanju, alakitiyan ati ẹni to ko ara rẹ ni ijanu.

Nipa ti idi to fi ma n jo lati polowo sinima rẹ to ba gbe ja’de, Funkẹ ni ko dede ri bẹẹ o, o ni aisi owo ipolowo lo kuku sun oun de bẹ, o ni sinima “Battle on Buka Street” l’oun ṣe tan l’oun ba ri pe ko yọ ọwọ ipolowo ọja silẹ l’oun ba da gba ọna ijo, pẹlu ṣiṣe fọnran ijo jijo l’ori ẹrọ ibanisọrọ rẹ lati polowo sinima naa ko to wa di ilana ti ọpọlọpọ awọn eeyan ti tẹ’wọ gba.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search