VDM Taku, O L’oun O Ni Yọ’ju S’awọn Ọlọpa To Ranṣẹ Si Ayafi

Ajijangbara l’ori ayelujara, Vincent Otse ti gbogbo eeyan mọ si VeryDarkMan lo ti gba lati jẹ ile-iṣẹ ọlọpa ilẹ wa ni ho lẹyin ti wọn kọ’we ranṣẹ si latari awọn ẹsun to fi kan oluranlowo igbakeji ọga olopa to n dari ẹka Zone 2, AIG. Moshood Jimoh, ti wọn ba ṣe igbesẹ naa ni eyi to n han si gbogbo aye.

O sọ eyi ninu atẹjade kan ti agbẹjọro rẹ, Dele Adeyanju fi lede, to si fi s’ori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ.

Eyi lo waye lẹyin ti ẹka to n risi iwadi iwa ọdaran ni ile-iṣẹ ọlọpa ilẹ wa l’Abuja f’iwe pe lati pese awọn ẹri maa jẹ mi niṣo silẹ lori ẹsun to fi kan AIG Jimoh.

Agbẹnusọ ile-iṣẹ ọlọpa ilẹ wa, CSP Ani Iniedu ti ni ile-iṣẹ ọlọpa ti ṣetan lati fi ilana to tọ ati ofin ilẹ wa mu ọrọ naa. Ile-iṣẹ ọlọpa kede pe awọn ti pe ọga ọlọpa naa fun ibeere lori awọn ẹsun ti wọn fi kan bẹẹ ni wọn kọ’we ranṣẹ si VDM lati wa fidi awọn ẹsun rẹ mulẹ.

Nigba ti wọn n fesi si ipe naa, awọn ikọ agbẹjọro VDM ni o ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpa ṣugbọn iwadi naa gbọdọ jẹ eyi to han si gbangba paapaa julọ nitori ipo ti ọga ọlọpa naa di mu.

VDM ni k’oun to le wa, awọn aṣoju ajọ awọn agbẹjọro nilẹ yii (NBA), awọn ajọ ti kii ṣe ti’jọba ati awọn olofintoto mii ti wọn o ba ijọba ṣiṣẹ, gbọdọ wa ni ikalẹ lati wo bi ifọrọwanilẹnuwo naa ṣe n lọ. Bẹẹ lo ni awọn ikọ agbẹjọro oun gbọdọ wa pẹlu oun titi ti ifọrọwanilẹnuwo naa fi maa tan.

VDM lo f’ẹsun kan AIG Moshood Jimoh ninu awọn fọnran  kan to fi lede lori ayelujara pe, o da ẹsun ipaniyan kan to wa l’akata rẹ ru, eyi lo fa ti awọn ọlọpa fi kọ’we ranṣẹ si lati wa fi ẹri han lori ẹsun naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search