Sam Larry F'arahan L'ẹyin Ijamba Ọkọ To Ni, Ẹ Wa Gbọ Ohun T'aye N Sọ Ni'pa Rẹ
Gbajumọ alafẹ to tun jẹ oniṣowo orin, Sam Larry ni o ti kuro n’ile-iwosan lẹyin ijamba ọkọ to fẹẹ gbẹmi rẹ.
Lẹyin ijamba ọkọ yii ni iroyin gb’ode kan pe o wa l’ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, eyi to mu ki ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria maa fi iṣẹlẹ naa mọ iku olorin Mohbad nigba naa, ti awọn kan si n kan mi nu si wiwa laye rẹ.
Sam Larry ni fọnran kan ti wa jade bayii, n’ibi to ti n yọ pẹlu olorin Fuji, Malaika lori ipe nibi ti olorin naa ti n kọrin ni ayẹyẹ kan.
Lẹyin fọnran yii, ni fọnran imi tun jade ni’bi ti o ti n yọ pẹlu awọn ọrẹ ati ojulumọ, to si n gbe ẹsẹ rẹ s’oke lati da iroyin pe wọn ti ge l’ẹsẹ nu. Ninu fọnran yii, ni awọn ọrẹ rẹ ti n kọrin ọtẹ pe Olorun doju ti awọn ti wọn fẹ ki wọn ge l’ẹsẹ.
Ọpọlọpọ ariwisi lo ti tẹle fọnran naa bayi, bi awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ṣe n bu ẹnu atẹ lu ajọyọ ti wọn n ṣe nigba ti ẹnikan ku ninu ijamba naa. Ọpọ awọn ti wọn sọrọ le fọnran ọhun ni wọn fi aidunnu wọn han pe ko si itara fun ẹṣọ rẹ to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ẹ ṣe iranti pe, Sam Larry lo ni ijamba ọkọ ni ọsẹ to kọja ni oju ọna onigberi-okun, Lagos Coastal Road leyi to fa iku ẹṣọ rẹ.