Mi O Ka'we Lootọ Amọ Ọpọlọ Mi Pe Ju T'ọpọ Awọn Alakọwe Lọ - MC Oluọmọ
Aarẹ ẹgbẹ ọlọkọ ẹrọ NURTW l’orilẹ-ede Naijiria, Musiliu Ayinde Akinsanya ti gbogbo aye mọ si MC Oluọmọ lo ti ni botilẹjẹ pe oun ko kawe, amọ ṣa ọgbọn ori oun ju ti ọpọ awọn alakọwe lọ.
MC Oluọmọ lo sọ eyi ni’bi ayẹyẹ ọjọ-ibi aadọta ọdun gbajugbaja olorin musulumi, Hafsat Adegoke to wa’ye ni’lu Eko.
Ni’bi ayẹyẹ yii gan-an ni MC Oluọmọ ti bẹrẹ si t’ẹnu bọ itan igbesiaye rẹ bo ṣe bẹrẹ gẹgẹ bii kondọ iyẹn agbero, Kẹrẹkẹrẹ titi to fi di ọkan ninu awọn igi nla l’awujọ awọn ọlọkọ ero. O ni irin-ajo naa ko kere rara, to si kun fun ọpọ ẹlẹkọ eleyii to gbe oun de ipo to wa l’oni.
Ko tan si’bẹ, MC ni bi oun o ti ẹ ka’we, gbogbo awọn ọmọ to n bi l’oun fun l’ẹkọ iwe to ye kooro, ti kaluku wọn si n gbe rere ṣe l’aaye wọn l’oni.
Siwaju si, Oluọmọ ni, ọrọ t’ẹnu kọ, bẹẹ ni kii ṣe igberaga, oun ti n f’owo ṣe fuja tipẹ lati kekere bi ọmọ ọdun mẹtala l’oun ti bẹrẹ si ni r’owo, gẹgẹ bi kondọ ti n pe’ro s’ọkọ, lati aagọ mejila ọsan si aagọ mẹfa irọlẹ. O ni oun a tun ma lọ wo ere awọn oyinbo India ni Danjuma Cinema pẹlu owo ara rẹ, to a sì tun lọ fun iya oun l’owo ounjẹ ọjọ.
Gbajumọ olori ọlọkọ ero naa ni oniruuru awọn iriri yii gan-an lo kọ oun bi eeyan ti n ṣiṣẹ karakara, ni aforiti ati li lee gbọ bukata, l’eyi to pada ṣina jijẹ adari fun-un.
Oluọmọ tun lo anfaani naa lati ṣe afọmọ ọrọ pe oun ko ja wọ idi iṣẹ naṣana iyẹn ẹgbẹ NURTWrara, iṣẹ ti oun kọ l’ẹsọ-l’ẹsọ t’inu-t’ode ni, k’oun to de’bi t’oun de. Oun le ma ka’we o ṣugbọn ọpọlọ oun pe daadaa ju aimọye awọn alakọwe miiran, ti oun ko si jẹ ki aikawe sọ oun di ero ẹyin.
L’akotan, MC Oluọmọ ni, b’oun o ti ẹ ka’we, ogo ni f’Oluwa nitori gbogbo awọn ọmọ rẹ l’oun fun l’ẹkọ iwe. Dokita nbẹ, lọya wa, ẹnjinnia naa wa ninu awọn ọmọ oun, ti wọn si wa l’orilẹ-ede Amẹrika ti wọn n ṣe daadaa. Ki Oluwa ma jẹ ki gbogbo abiamọ f’oju sunkun ọmọ.