Kilọbu Ni’le Ijo Ni Mo Ti Pade Aya Mi To Si Pada Wa J’aya Rere – Vector

Kilọbu Ni'le Ijo Ni Mo Ti Pade Aya Mi To Si Pada Wa J'aya Rere - Vector

Inkọrin takasufe, Olanrewaju Ogunmefun, ti gbogbo eeyan mọ si Vector Tha Viper lo ti ni ile-ijo ni oun ati iyawo oun, Yinka Coker ti pade.

Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, Vector ni, ka gbe ti ero pe awọn ọmọbinrin ti eeyan ba pada ni’le ijo kii jẹ iyawo gidi s’ẹgbẹ, pẹlu pe ile-ijo l’oun ti pade iyawo oun, iyawo ile gidi ni.

 

Onkọrin naa sọ eyi pẹlu bi o ṣe n jiyan pe kii ṣe dandan lati tẹle ohun ti awujọ la kalẹ nigba ti eeyan ba fẹ mu iyawo abi ọkọ, paapaa julọ, nipa ibi ti eeyan ti le pade.

O ni pẹlu pe ile-ijo l’awọn ti pada, iyawo to f’idi mọ’le ni. O fi kun pe eeyan o le gba imọran nipa ọkọ abi iyawo fifẹ.

Onkọrin naa ni, oun o ni ki ẹnikẹni ma gba imọran rara. O ni o daa lati ni awọn eeyan diẹ ti eeyan le gba imọran lọwọ wọn ṣugbọn o da ki eeyan ro daadaa ko to pinnu.

Vector ati iyawo rẹ, Yinka Coker ni wọn ṣe igbeyawo ni ọdun 2022, ti wọn si bi ọmọbinrin kan.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search