Davido Sọrọ Gba MC Oluomo L'ori Lori Ọrọ Ẹgbẹ Ọlọkọ NURTW L'Ọṣun
Gbajugbaja onkọrin David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Davido ti bu ẹnu atẹ lu aarẹ ẹgbẹ ọlọkọ NURTW l’orile-ẹde Naijiria, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluomo lori bo ṣe tako idaduro iṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Osun.
Gomina Ademola Adeleke lo da iṣẹ ẹgbẹ NURTW duro ni awọn ibudo ọkọ kaakiri ipinlẹ Ọsun latari ija to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa ati awọn ẹgbẹ awakọ mii.
Latari idaduro yii, ijọba ipinlẹ Ọsun wọgi le owo irinna ti ẹgbẹ naa maa n gba bẹẹ ni wọn paṣẹ fun awọn ẹṣọ alaabo lati fi ọwọ ofin gbe ẹnikẹni to ba n ṣiṣẹ l’orukọ ẹgbẹ naa.
Nigba to n gbẹnu igbakeji, Aliyu Issa Ore sọrọ nibi ifilọlẹ kan, MC Oluomo tẹnpẹlẹ mọ pe ijọba o ni agbara lati da iṣẹ ẹgbẹ naa duro nitori awọn o si labẹ ijọba ipinlẹ kan-kan.
Nigba to n fesi si ọrọ ti MC Oluomo sọ yii, Davido lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ lo ti fi aarẹ ẹgbẹ naa ṣe yẹyẹ pe puruntu ni. O ni ṣe MC Oluomo ti o le da gbolohun kan kọ lo n sọrọ.
Ọrọ yii ti wa fa ariyanjiyan lori ipa ti awọn ẹgbẹ ọlọkọ n ko ninu oṣelu ati eto idibo l’orilẹ-ede Naijiria t’oun ti iṣẹ wọn ni pato.