Ko Si'ja Laarin Emi Ati Funkẹ, Ẹ Ye Gbe Iroyin Ofege Kiri - Kamo State
Gbajugbaja agbefọnran apanilẹrin jade lori ayelujara, Akinyoola Ayoola, ti ọpọ eeyan mọ si Kamo State, lo ti ko iroyin pe oun ati oṣerebinrin Funke Akindele o jọ ṣe papọ mọ danu, to si n ni awọn ṣi jọ wa pẹkipẹki pẹlu pe awọn eeyan o ri awọn papọ mọ bii ti tẹlẹ.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, adẹrinpoṣonu naa ni idi ti awọn eeyan o fi maa ri awọn papọ nigboro bii ti tẹlẹ ko ju pe iṣẹ ti pọ f’awọn mejeeji.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn mejeeji o jọ raye mọ nitori iṣẹ leyi to fa ki awọn ma le ni akoko pupọ papọ mọ bii ti tẹlẹ.
Kamo wa rawọ ẹbẹ s’awọn ololufẹ ati awọn eeyan ori ayelujara lati ye gbe iroyin ofege ka nitori ko si ija kan-kan laarin awọn.
Nigba to n sọrọ lori bi ibaṣepọ wọn ṣe bẹrẹ, o ni, o tipẹ t’oun ti nifẹ si Funke nitori o jẹ ọkan lara awọn oṣere t’oun n wo l’oke.
O ni ifẹ to ni si iṣẹ oun lo fa t’oun fi n pe ni iya ati pe igbagbọ to ni ninu oun lo ṣe fun oun laye ninu awọn sinima rẹ.
Ọrọ ti Kamo sọ yii lo jẹyọ lẹyin ti ọpọ awọn eeyan lori ayelujara gbe iroyin pe wọn o si papọ mọ latari bi wọn o ṣe jọ n wa ni ayẹyẹ ati ibi iṣẹ mọ bii ti tẹlẹ.