Ile-iṣẹ ọlọpa ilẹ wa ti fi ọwọ osi juwe ile fun awọn ripẹtọ (Inspector) ọlọpa marun-un ni ipinlẹ Rivers lori ọran pe wọn di’panpa lati ṣiṣẹ laabi bii idigunjale, ijinigbe, ifungunmọni ati bẹẹ bẹẹ lọ nilu Port Harcourt ati agbegbe rẹ.
Agbẹnusọ fun ile-Iṣẹ ọlọpa Anthony Placid sọ eyi di mimọ ni’gba to n ṣe afihan awọn maraarun naa ti orukọ wọn n jẹ John Okoi, Eyibo Asuquo, Udo Ndipmong, Bright Nwachukwu ati Anele Ikechukwu.
Awọn marun-un yii ni iwadii fi han pe wọn wa ninu awọn ẹgbẹ ọdaran kan ti wọn n f’iṣẹ ọlọpa boju lati jinigbe, jale ati fi tipa gba owo lọwọ awọn ara-ilu.
O ṣalaye pe iwadi tun fi han pe awọn ọdaran naa ma n lo ọkọ Sienna ti wọn si n fi iwọde ọlọpa ṣe bojuboju ti wọn a si da awọn olugbe duro ṣe ayẹwo ọkọ tio b’ofin mu ti wọn a si fi tipa mu awọn tọwọ wọn ba tẹ lati si ẹrọ ibanisọrọ wọn lati wọ owo to wọ miliọnu kuro ninu apo ifowopamọ wọn.
Agbẹnusọ naa ṣalaye pe iwadi orikiniwin lo tu aṣiri awọn oniṣẹ laabi si’ta, ti gbọnmọgbọnmọ iṣẹ wọn si pọ laarin oṣu kẹsan ọdun to kọja si oṣu kini ọdun yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ awọn ọdaran yii maa n ko awọn to ba ko sakolo wọn lọ sinu igbo ti wọn a si lu wọn titi.
Lara awọn nkan ti wọn ri gba lọwọ awọn ọdaran naa ni ọkọ Sienna mẹta ati owo to ju miliọnu meje naira.
Placid ṣalaye pe awọn ọlọpa to yẹ ki wọn fi ṣikun ofin gbe awọn ọdaran naa ti wọn kọ naa ma jiya pe wọn o ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ.
Agbẹnusọ naa wa tẹnpẹlẹ mọ pe ile-iṣẹ ọlọpa ṣe tan lati gbogun ti awọn kanda inu irẹsi ti wọn n ba iṣẹ ọlọpa loju jẹ ati pe iwa awọn ọdaran yii ko gba ibi kankan jẹ ti awọn ọlọpa rara.