Emi O Si Lẹyin Oloṣelu Kan-kan – Skales

Emi O Si Lẹyin Oloṣelu Kan-kan - Skales

Onkọrin takasufe nni ti awọn eeyan nifẹ si, Raoul John Njeng-Njeng ti inagijẹ rẹ n jẹ Skales lo ti ṣalaye ero rẹ lori oṣelu

Alaye yii lo ṣe lẹyin ti awọn eeyan bu ẹnu atẹ lu lori ọrọ to sọ laipẹ yii nipa oṣelu ilẹ wa.

Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ, Skales ni oun o ba ẹgbẹ oṣelu kan-kan tan bẹẹ l’oun o ṣatilẹyin fun oloṣelu kan-kan ninu awọn ti wọn n dije dupo bayii.

 

O tẹsiwaju pe gbogbo iṣejọba ti ko lọ deede yii kan oun naa nitori orilẹ-ede Naijiria l’oun n gbe.

O tẹnpẹlẹ mọ pe ki awọn eeyan ma ka ọrọ t’oun sọ lati bu ẹnu atẹ lu ijọba bii atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu alatako kan-kan, bẹẹ lo ni orilẹ-ede Naijiria nilo awọn to daa ju awọn tiwọn n dije l’ọwọ lọ.

Ọrọ yii lo jẹyọ lẹyin ọjọ diẹ ti olorin naa jade lati wa ko ọrọ kan to n lọ lori ayelujara danu pe awọn kan san’wo fun lati ti ọrọ oṣelu kan lẹyin.

Ninu ọrọ kan to fi lede tẹlẹ, Skales ni ko si ẹnikẹni to san owo kan-kan fun oun, ni ṣe l’oun mọọmọ jina si oṣelu nitori oun o ni gbagbọ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu to ṣe gboogi lorilẹ-ede yii mọ.

Lẹyin ohun to kọ yii, awọn ololufẹ rẹ kan gboṣuba kaare fun nitori ko ti ẹgbẹ oṣelu kan-kan lẹyin.

Skales lo ja gbangba nidi iṣẹ orin ni ọdun 2009 labẹ onkọrin Banky W.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search